Home / Àṣà Oòduà / Fayose setan lati ya awon osise lowo ra moto nipinle Ekit

Fayose setan lati ya awon osise lowo ra moto nipinle Ekit

“Ilaji owo osu won nijoba yoo ma yo fi san gbese naa” -Komisanna isuna owo

Gomina Ayodele Fayose ti yanda owo to le ni igba milionu owo naira (N236,860,000) gege bi owo ti won ya soto lati ya awon osise ipinle Ekiti lati fi ra orisii moto to ba wu won.

Komisanna eto isuna ipinle Ekiti, Toyin Ojo, so wi pe, awon osise ti anfaani naa si sile fun yoo ni anfaani lati ya owo to to egberun lona ogorin (N80,000) si milionu kan abo (N1.5m), eleyii ti won yoo tewo gba lodindi.

 

Komisanna tun so siwaju wi pe, ki i se gbogbo osise ni o leto si anfaani yii bikose awon kan ti won ti n sise siru ilu fun awon akoko kan ati ipo won lenu ise ijoba.

Lara afikun komisanna ni wi pe, awon osise ti won ba setan lati je anfaani yii ni lati fara mo ilana ati agbekale to wi pe, ilaji owo osu won ni ijoba yoo ma yo lati fi kase gbese naa nile. Bakan naa lo tun fi n da awon osise to ku loju wi pe, laipe, anfaani owoya lati fi ra moto ara eni yoo kari gbogbo won pa.

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Akasu oro Fayose: “Eni ba fori so mi, yoo fo yangayanga”

Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Peter Fayose, ti fi da gbogbo ara ilu loju wi pe didun losan yoo so fun egbe alaburada, PDP, ninu eto idibo alaga ibile eleyii ti yoo waye lojo kokandinlogun osu kejila odun yii (19-12-15). Sugbon gege bi atejade akowe ipolongo fegbe APC, Ogbeni Taiwo Olatunbosun,  so wi pe awon ko ni igbagbo ninu igbimo ti n se kokari eto idibo naa, Ekiti State Independent Electoral Committee, ESIEC. O ni pupo awon omo igbimo naa lo ...