Home / Àṣà Oòduà / Atitare/Itare: Pataki ewe towa ninu aworan yi ninu odu ifa OTURA ORILANA

Atitare/Itare: Pataki ewe towa ninu aworan yi ninu odu ifa OTURA ORILANA

Aku ise ana o oni a sanwa o, aanu olorun Olodumare koni fiwa sile loni o ase.
Laaro yi mofe ki e mo Pataki ewe towa ninu aworan yi ninu odu ifa OTURA ORILANA, ati iwulo e ti o se je ikan gbogi lara ewe ti a fi nwe ifa.

 
Ewe yi je ewe to dara lati maa fi we ifa wa nitori yio mu abawon buburu kuro lara re, ninu odu ifa OTURA ORILANA yi ewe yi wa lara awon ewe ti a maa nlo lati fi se ose ifa fun eniti odu ifa yi ba bi nigbodu tabi won dafa fun ti odu yi si jade si, ose yi je ose ifa to dara lati maa lo nitori yio mu owo buburu kuro lara, yio we Okuta, ikorira, aita oja ati arunkarun kuro lara wa patapata.

 
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila lo di àtàmójàyá, emi naa mo lo di àtàmójàyá
Orunmila ni ki won sofun sòwòsòwò otu ife ko fi okoo kanri kandi re kofi leri oun ifa nitori ki oja re baa le maa ya
Orunmila lo di àtàmójàyá, emi naa mo lo di àtàmójàyá
Orunmila ni ki won sofun ògàrè otu ife ko fi okoo kanri kandi re kofi leri oun ifa nitori ki o ba le fiwaju feyingun pelu irorun
Orunmila lo di àtàmójàyá, emi naa mo lo di àtàmójàyá
Orunmila ni ki won sofun àgbé otu ife ko fi okoo kanri kandi re kofi leri oun ifa nitori ki o baa le roko bodunde
Orunmila lo di àtàmójàyá, emi naa mo lo di àtàmójàyá
Orunmila ni ki won sofun sorunsorun otu ife ti won nsun orun òkù ko fi okoo kanri kandi re kofi leri oun ifa nitori ki o ma baa maa sorun oku mo
Moni Orunmila kilode ti o fi nfo bi ede bi eyo? Orunmila loun ko fo bi ede bi eyo oni akapo toun ti won da oun ifa fun loun nba wi wipe ki o fi okoo kan ori ati idi re ki o fi leri oun ifa ki o maa baa maa sorun oku mo, moni akapo re ti se bo se so Orunmila
Oni ki won sofun wipe ki o lo ni ewe atitare, ewe aje sefunsefun, ewe baja, ewe bojo, ewe agungunmaga ti ki nje kibi o sele nile awo………….ati ose dudu ki won maa fi se ose ifa fun, oni òkùtà, ijakule, amubo ati aseti yio kuro ninu aye re patapata.
AKOSE: Ao gun awon elo wonyen papo mose dudu ao gbaye ifa naa si ao ko ose naa sinu aso funfun eni naa yio maa fi we. Hmm! Ose ifa yi daju debipe gbogbo owo buburu to nbe lara re yio kuro, yio segun ikorira ati Ogun amubo, aseti ati ijakule ara re patapata.
Eyin eniyan mi, mogbaladura laaro yi wipe eledumare yio mowo buburu kuro ninu aye wa, Ogun ikorira ati ijakule yio di ohun igbagbe ninu igbesi aye wa, ona ire gbogbo yio la funwa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO

 

 

English Version:

Continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo