Home / Àṣà Oòduà / Ògúndá Ọ̀wọ́nrín (Ògúndẹ̀rín)

Ògúndá Ọ̀wọ́nrín (Ògúndẹ̀rín)

Àtẹ́lẹwọ́ mi ọ̀tún ni mo fi kọ́’fá ń dídá
Mo mọ Ifá ń dídá
A dífá fún Akítán tíí ṣe ọmọ’yè Oníkàá
Àtẹ́lẹwọ́ mi òsì ni mo fi kọ́bò ní gbígbà
Mo mọ ìbò ni gbígbà

Dífá fá fún Aṣọ̀gbà tíí ṣe ọmọ Ẹkùn ni Ìròkò
Kádífá káyẹ̀gẹ̀ – káyẹ̀gẹ̀ Kádífá
Dífá fún Òrógbòńdú tíí ṣe ọmọ ọba lálède Òwu
Bòkun wẹrí
Dífá fún Lààlà tíí ṣe ọmọ ọba ẹ̀yìn Ìkosùn

Bọ̀ṣà wẹsẹ̀
Dífá fún Òbé tíí ṣe ọmọ ọba lálède Ọ̀yọ́
Ẹ ̀bá bòkun wẹrí
Ẹ bá bọ̀sà wẹsẹ̀
Ẹni Ọlọ́run báwẹ̀ ni mọ́ ṣáká ṣáká

A dífá fún Abírí eléyìí tí kìí ṣe ọmọ Olóyè kọ́ọ̀kan.
Àwọ́n le rí ire lọ́pọ̀ lọ́pọ̀ ni wọ́n jí
Ni wọ́n ń dáfá ṣí
Ẹbọ làwọn Awo ní wọ́n ó ṣe
Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà dẹbọ sílẹ̀

Wọ́n rú u
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sí ìgbà náà
Akítán tíí ṣe ọmọ’yè Oníkàá
Gun orí oyè bàbá rẹ̀
Wọ́n mú un jẹ́ Oníkàá

Bákannáà ni Aṣọ̀gbà joyè Ẹkùn ni Ìròkò
Ọ̀rógbòńdú di Olówu tuntun lẹ́yìn tí baba rẹ̀ gbéṣẹ̀
Lààlà jẹ́ ọba Onígosùn lẹ́yìn tí baba rẹ̀ fi ọwọ okùn lélẹ̀
Wọ́n tún mú Òbé jẹ Aláàfin lẹ́yìn tí ilẹ̀ bàjẹ́ ní Ọ̀yọ́
Ó wá ku Abírí tí kìí se ọmọ Olóyè kọ́ọ̀kan

Kòsí oyè kan ṣoṣo nílẹ̀ tí ó lè jẹ
Lẹ́yìn ikú bàbà rẹ̀
Ni o bá gba ọ̀dọ̀ Aláàfin lọ ní Ọ̀yọ́
Șùgbọ́n, wọn kò jẹ́ kó rí Aláàfin
Wọ́n ní irọ́ ni ó ń pa pé ọ̀rẹ́ Aláàfin ni òun láti ìgbà kékeré àwọn

Ìgbà náà ni ó wà dá ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀
Ó gba ìdí Ọ̀pẹ̀ Àgùnká tí ìlú ń bọ lọ́dún lọ
Ó ń fi àáké gé e kára kára
Wọ́n bá mú un lọ sí Ààfin lọ́dọ̀ Ikú Bàbá Yèyé
Nítorí wípé ó ní Aláàfin fún ara rẹ̀ ló rán òun níṣẹ́

Ìgbà tó fojú kan Aláàfin ló ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀bẹ̀ ọ̀ràn
Ó wá bẹ̀rẹ̀ ìtàn ara rẹ̀ ní pípa
Ó ṣe àlàyé bí àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ṣe dáfá
Bí àwọn ti ṣe rúbọ rẹ̀
Tí Ifá àwọn márùn-ún ṣe ti ṣẹ

Tí ó wá kú ti òun nìkan ṣoṣo
Ní ibi tí Aláàfin gbé ń ṣe ìgbẹ́jọ́ yìí lọ́wọ́
Ni wọ́n ti wá túfọ̀ fún un
Pé Baṣọ̀run tí ṣe olórí àwọn Ọ̀yọ́ Mèsì
Tí ó tún jẹ́ igbá-kejì Aláàfin tirè ìwàlẹ̀ àṣà

Aláàfin kò ṣe méní ṣe méjì
Ló bá fi Abírí ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ tijọ́ jẹ oyè Baṣọ̀run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sí sílẹ̀ lọ́jọ́ náà
Ó ní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ làwọn Babaláwo tòun ṣe fẹnu rere ki’fá
Àtẹ́lẹwọ́ mi ọ̀tún ni mo fi kọ́’fá ń dídá
Mo mọ Ifá ń dídá

A dífá fún Akítán tíí ṣe ọmọ’yè Oníkàá
Àtẹ́lẹwọ́ mi òsì ni mo fi kọ́bò ní gbígbà
Mo mọ ìbò ni gbígbà
Dífá fá fún Aṣọ̀gbà tíí ṣe ọmọ Ẹkùn ni Ìròkò
Kádífá káyẹ̀gẹ̀ – káyẹ̀gẹ̀ Kádífá

Dífá fún Òrógbòńdú tíí ṣe ọmọ ọba lálède Òwu
Bòkun wẹrí
Dífá fún Lààlà tíí ṣe ọmọ ọba ẹ̀yìn Ìkosùn.
Bọ̀ṣà wẹsẹ̀
Dífá fá fún Òbé tíí ṣe ọmọ ọba lálède Ọ̀yọ́

Ẹ ̀bá bòkun wẹrí
Ẹ ̀bá bọ̀sà wẹsẹ̀
Ẹni Ọlọ́run báwẹ̀ ni mọ́ ṣáká ṣáká
A dífá fún Abírí eléyìí tí kìí ṣe ọmọ Olóyè kọ́ọ̀kan

Àwọn le rí Ire lọ́pọ̀ lọ́pọ̀ ni wọ́n jí
Ni wọn ń dáfá sí
Àwọn gbẹ́bọ níhàbẹ̀
Wọ́n rúbọ
Ǹjẹ́ a ti mú Abírí jẹ Ọṣọ̀run

Ẹyìnwà
Kí ẹni má ro Ẹ̀dú pin
Ẹ̀yìnwà
Ǹjẹ́ a ti mú Abírí jẹ Ọṣọ̀run ná
Ẹ̀yìnwà
Kí ẹni má ròmí pin
Ẹ̀yìnwà

Ire ni .

About Awo

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo