Home / Àṣà Oòduà / A ti gba 800 bílíọ̀nù owóòlú tí wọ́n jí kó, àwọn 1,400 ti dèrò ẹ̀wọ̀n– Lai Mohammed

A ti gba 800 bílíọ̀nù owóòlú tí wọ́n jí kó, àwọn 1,400 ti dèrò ẹ̀wọ̀n– Lai Mohammed

A ti gba 800 bílíọ̀nù owóòlú tí wọ́n jí kó, àwọn 1,400 ti dèrò ẹ̀wọ̀n– Lai Mohammed

Ẹdìyẹ ń làágùn, ìyẹ́ ni kò jẹ́ kó hàn.
Ìjọba àpapọ̀ ti sọ pé òun ti gba owó tó lé ní ẹgbẹ̀rin bílíọ̀nù náírà padà lọ́wọ́ àwọn tó jíi kó.

Mínísítà fún ètò ìròyìn àti àṣà, Lai Mohammed ló kéde bẹ́ẹ̀ níbi ìpàdé àwọn akọròyìn kan tó wáyé ní ìlú Àbújá.

Ó fi kún un pé egbèje èèyàn ló ti ń faṣọ péńpé roko ọba báyìí lẹ́yìn tí aje ìwà àjẹbánu ṣí mọ́ wọn lórí.

Ó ṣàlàyé pé “Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ìjọba tó wà lóde yìí ń dojú ìjà kọ ìwà jẹgúdújẹrá, a sì ní ẹ̀rí láti gbè é lẹ́sẹ̀.”

Mínísítà ọ̀hún tẹ̀ síwájú pé “Ìjọba yìí ní àkọsílẹ̀ àwọn egbèje èèyàn tó wà ní àhámọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ti gba owó tó lé ní ẹgbẹ̀rin bílíọ̀nù náírà padà, yàtọ̀ sí àwọn ohun ìní tí a gbẹ́sẹ̀lé”

Ó ní yàtọ̀ sí gbígba owó Ìjọba tí àwọn èèyàn ìlú kan lù ní póńpó padà, Ìjọba tó wà lóde yìí, lábẹ́ àkóso Ààrẹ Buhari tún ń ṣètò ìyípadà ọkàn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà, kí ìwà àjẹbánu leè di ohun ìgbàgbé.

Lai parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lu akitiyan Ìjọba tó wà lóde yìí ronúpìwàdà, kí wọ́n sì dojúkọ àṣeyọrí tí Ìjọba ń ṣe láti paná ìwà jẹgúdújẹrá lórílẹ̀-èdè yìí.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Ìjo̩ba máa gbé pé̩ré̩gi kaná pè̩lú àwo̩n oníròyìn ìdàlúrú – Lai Mohammed

Minisita fun eto iroyin ati asa ni orileede yii, Alhaji Lai Mohammed ni ijoba apapo ko ni gba ki awon kan fi iroyin aboosi da ilu ru. O ni “oloju ko ni laju re sile ki talubo woo”. O ni aseju awon ti won pe ara won ni aja fun eto omoniyan ti po ju. O ni orisiirisii iroyin to le da ilu ru, to le da irewesi si okan awon to n femi sise ilu ni won n gbe ...