Home / Àṣà Oòduà / Akasu oro Fayose: “Eni ba fori so mi, yoo fo yangayanga”

Akasu oro Fayose: “Eni ba fori so mi, yoo fo yangayanga”

Gomina ipinle Ekiti, Ayodele Peter Fayose, ti fi da gbogbo ara ilu loju wi pe didun losan yoo so fun egbe alaburada, PDP, ninu eto idibo alaga ibile eleyii ti yoo waye lojo kokandinlogun osu kejila odun yii (19-12-15).

Sugbon gege bi atejade akowe ipolongo fegbe APC, Ogbeni Taiwo Olatunbosun,  so wi pe awon ko ni igbagbo ninu igbimo ti n se kokari eto idibo naa, Ekiti State Independent Electoral Committee, ESIEC. O ni pupo awon omo igbimo naa lo je awon omo egbe PDP, eleyii si wa lara ohun to mu Fayose fokan bale.

Sugbon gege bi oro Fayose, eni odun marunlelaadota (55), salaye wi pe aileja nita baba mi ko de hin-in. “Omi ti tan leyin eja awon omo egbe APC ti ipinle Ekiti lo mu won ma japoro bi eni won ta lofa,” Fayose fi kun oro re bee.

Rugudu to waye latari wi pe egbe onigbale, APC, ko faramo awon igbimo ajo ti o seto idibo naa lo ti pada dele ejo bayii.

“E je ki gbogbo wa ka pade nile ejo. Enikeni ko le da eto idibo naa duro ayafi ohun ti ile ejo ba so lojo kerinla osu kejila odun yii,” Fayose tun fidi re mule bee.

Gege bi alaga igbimo. Eto idibo fun ipinle Ekiti, Onidajo-feyinti Kayode Bamisile, so wi pe iro funfun balau ni wi pe awon omo igbimo oun je omo egbe oselu kan. O si fi kun un wi pe, enikeni to ba ni eri to daju le fi sita. Alaga naa ko sai kede ojo Satide ti n bo, 19-12-15, gege bi ojo ti eto idibo naa yoo waye.

Wayio, ogbeni Owen Chigozie Ewenike, okan ninu awon oludije fun ipo kanselo adugbo lagbe egbe oselu PDP ti gbe oriyin fun gomina Fayose fun anfaani to fun un lati kopa ninu eto idibo to n bo naa.

Ti e ko ba gbagbe, nnkan bi osu meloo kan seyin ni Gomina Fayose fi atejade kan sita, eleyii ti oludamoran re nipa iroyin ayelujara, Lere Olayinka gbe jade faraye ri. Ninu atejade yii ni ogbeni Fayose ti n ju akasu oro ribiti fun awon alatako re:
“Ni ipinle Bauchi nibi ti alaga egbe PDP apapo ati minisita fun ilu Abuja ti wa, won ko ri ida marun-un ninu ogorun (5%) ibo mu fegbe PDP.

“Ninu eto idibo aare to waye, mo bori ibo naa fun PDP nipinle Ekiti, mo bori gbogbo ibo asoju ile igbimo asofin agba ati asoju-sofin Abuja, mo tun bori gbogbo ibo omo ile igbimo asofin ipinle ti apapo won je merindinlogbon (26) fun egbe oselu PDP l’Ekiti.

“Mo dabi Isireli ti awon ota dooyi yika, sugbon to n leke saa nigbogbo ojo. Peteru ni oruko mi, eyi to tunmo si apata. Ti enikeni ba fori so mi yoo fo yangayanga, ti mo ba subu lu enikeni, maa lo luulu. Fun idi eyi, e fi apata sile jeje o.” – Fayose

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Fayose setan lati ya awon osise lowo ra moto nipinle Ekit

“Ilaji owo osu won nijoba yoo ma yo fi san gbese naa” -Komisanna isuna owo Gomina Ayodele Fayose ti yanda owo to le ni igba milionu owo naira (N236,860,000) gege bi owo ti won ya soto lati ya awon osise ipinle Ekiti lati fi ra orisii moto to ba wu won. Komisanna eto isuna ipinle Ekiti, Toyin Ojo, so wi pe, awon osise ti anfaani naa si sile fun yoo ni anfaani lati ya owo to to egberun lona ogorin ...