Home / Àṣà Oòduà / Àsírí Òkété

Àsírí Òkété

ÒKÉTÉ.
___
Òkété jẹ́ ọ̀kan nínú ẹranko abàmì tó lágbára púpọ̀. A sì máa gbé nínú ihò. ELÉDÙMARÈ fún-un ní àṣẹ púpọ̀.
Òkété kìí fi ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ gbẹ́ ihò, ÌRÙ ni òkété maá n fií gbẹ́ ihò, fún ìdí èyí, ẹ ò le rí èrùpẹ̀ lẹ́nu isà òkété, bí ènìyàn bá gbẹ́ ihò òkété, ìgbà mìíràn a máa sé isà mọ́ èèyàn lọ́wọ́.

Tí abá gbẹ́ isà kan, òkété tí ó bá fi ahọ́n rẹ̀ Kan ilẹ̀, kò sí olúwarẹ̀ tí ó le ríi fà jáde.
Òkété tún ní àṣẹ kan ní ìparí Ìrù rẹ̀, bí ènìyàn bá n lé òkété lọ, tí ó bá fi àṣẹ Ìrù rẹ̀ na ilẹ̀, kò sí bí ẹni náà tile lágbára tó, yó subú lulẹ̀, àwọn ìdí èyí ló bí òwe Yorùbá tó sọ wípé
”Ọ̀RỌ̀ T’ÓKÈÉTÉ BÁ BÁ ILẸ̀ SỌ NI ILẸ̀ Ẹ̀ GBỌ”.

Tí ènìyàn bá pa òkété tí ẹni náà bá gé àṣẹ ìrù rẹ̀ sínú isà òkété náà, òkété náà yóò tún da padà wọ inú isà náà lẹ́yìn ọdún kan, èyí ló sì tún bí òwe Yorùbá tó sọ pé
”MI O LÈ FI ILẸ̀ BABA MI SÍLẸ̀, LÓ N S’EKÚ P’ÒKÉTÉ L’Ọ́DỌỌDÚN”.

Tí Òkété bá ti b’ímọ yóò yọ yàrá fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú Isà kan náà, wọn yóò yọ pálọ̀ síbẹ̀ èyí ni à n pè ní AGBURU ÒKÉTÉ, ibẹ̀ ni gbogbo wọn tí máa n jẹun.
Tí òkété bá ti darúgbó dáadáa tí ẹnu rẹ kò ran oúnjẹ mọ, àwọn ọmọ rẹ tí ó jẹ́ abo ni wọ́n ó ma fún-un lọ́yàn mu, èyí ló tún bí òwe Yorùbá tí ó sọ wípé
”BÍ ÒKÉTÉ BÁ DÀGBÀ, ỌMÚ ỌMỌ RẸ̀ NÍÍ MU”.

Òkété fẹ́ràn ÈKÙRỌ́ púpọ̀, ẹ̀kùrọ́ tí a bá rí nínú isà òkété, a kìí pèé ní èkùrọ́ ÈSÉ ni a má n pèé. Èyí ló bí òwe àwọn Yorùbá tó sọ wípé:
”KAKA KI OKETE MAJE EESE A FI SAWADANU NI”.

Òkété a máa dìde rìn bí ènìyàn lọ́gànjọ́ òru, yóó sì kó oúnjẹ lọ́wọ́ tàbí kí ó gbe oúnjẹ rù s’órí, ọdẹ tàbí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pa irú òkété tóbá wà ní ipò náà.

Orúkọ mìíràn fún òkété ni EWÚ, òkété Kìí jáde ní ọ̀sán. Èyí ló bí òwe ”A KÌÍ RÍ EWÚ LỌ́SÀN-ÁN”.
Tí ènìyàn bá gbẹ́ Isà kan òkété tàbí tó bá gbé àwọ̀n lélẹ̀, a ò gbọdọ̀ fa ìrù òkété yìí Jù kí ìrù rẹ̀ má baà bó, tí òkété bá b’órù mọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àmúbọ́ ló n fà.

Tí ènìyàn bá pa òkété tó n sùn lọ́wọ́ tó sì bu eérú sí ojú ọ̀nà rẹ̀, yóò rí ojú ẹṣẹ̀ òkété tó ti jáde padà, èyí ló mu àwọn àgbà máa pèé ní ÀKÚDÀÁYÀ….

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo