Home / Àṣà Oòduà / Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Ṣé Ìwọ mọ pé gbogbo agboolé nílùú Igbóọrà ní wọn ń bí ìbejì ?

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé kò sí ìlú tí kò ní àdámọ́ ọ ti ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí nílùú Igbóọrà .Igbóọrà jẹ́ ìlú kan tó kalẹ̀ si agbègbè Ìbàràpá nipinlẹ Ọyọ, tí ìgbàgbọ́ sì wà pé kò sí ile kan nínú ìlú náà tí wọn kò ti bí ìbejì ìbẹta tàbí ìbẹrin níbẹ̀.

Kódà, àwọn ọmọ bíbí ìlú àti àwọn a àjèjì tó bá ń gbé nínú ìlú, tó ń jẹ oúnjẹ wọn, tó sì ń mu omi wọn, ni okun ìbejì àbi ìbẹta wà nínú rẹ̀.
Ọdọọdún sì ni wọ́n máa ń ṣe ọdún ìbejì nílùú náà, èyí tó tun kò lọdun yii.
Ọ̀kan lara àwọn ọba alaye ìlú Igbóọrà, Ọba Adedamọla
Badmus, tíí ṣe Olu-Aso ti Ìbẹ̀rẹ̀kòdó sọ fáwọn oníròyìn pé, ìgbàgbọ́ wà pé ọbẹ̀ ìlasa àti àmàlà dúdú ló ń sokùnfà ìbí púpọ̀ nílùú ọhun.

Gẹ́gẹ́ bí ọba Badmus ti wí, o ti to aadọta ọdun sẹyin ti ilu Igbóọrà ti gbajúmọ̀ nípa bíbí ìbejì àbi ìbẹta, ohun tó sì tun jẹ́ pàtàkì ni pé, wọn kìí fi ìbejì tọrọ owó nílùú Igbóọrà. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé gbogbo ìdílé t’áwon ọmọ náà bá yà ni wọn má a ń kóríire ràn .

http://iroyinowuro.com.ng/2019/10/18/%e1%b9%a3e-iwo-mo-pe-gbogbo-agboole-niluu-igboora-ni-won-n-bi-ibeji/

About ayangalu

x

Check Also

ojo keji

Ó San Owó Ilé Ìwé Mi Títí Mo Fi Jáde, Ṣùgbọ́n Mo Fi Májèlé San!

Àti ilé ìwé e gírámà ni èmi àti Kọ́lá ti jọ ń fẹ́ ra wa. Àwọn òbí i mi ò kí ń fẹ́ rí Kọ́lá pẹ̀lú u mi nítorí ààfín ni. Nígbà tí mo fẹ́ wo ile ìwé gíga ni bàbá à mi ní àìsàn an rọ́pá, rọsẹ̀,ọpẹ́lọpẹ́ kọ́lá tó san owó ilé ìwé è mi láti ìgbà tí mo wolé ẹ̀kọ́ gíga títí mo fi jádé. Nígbà ti mo lọ ṣe agùnbánirọ̀ mo pàdé sẹ́nátọ kán,èmi àti ẹ̀ sì ...