Àwon olùgbé Opolo ní Yenagoa ìpínlè Bayelsa ni ìbèrùbojo ti gba okàn won léyìn tí àwon adigunjalè jà won lólè tán.
Gégé bí ìròyìn se so, àwon olè yí kojá ogbòn tí won sì gbé àwon ohun ìjà olóró lówó bíi Ìbon, òbe, àkéé lówó, tí won fi lo ká arábìnrin tí a mò sí Jane nílé pèlú àwon míràn náà.
A gbo wípé owó tí àwon olè yí jí lo kò ní ònkà pèlú àwon nkan míràn náà nígbà tí won wolé síwon lára tán, won wolé siwon lára láti ojú fèrèsì.
A gbo wípé àwon adigunjalè yí lo láì sí eni kankan láti yèwón lówó wò. Àti wípé won kò pa enikéni bí kò se wípé won fi àpá sí àwon kan lára.
Àwon ará àdúgbò n bèrè fún àbò tí ó péye láti gbawón lówó irú ìsèlè náà.
Home / Àṣà Oòduà / Àwon tí ó n gbélè sunkún síta fún ìrànlówó nígbà tí àwon adigunjalè jàwón lólè ní Bayelsa.
Tagged with: Àṣà Yorùbá