Home / Àṣà Oòduà / Buhari kí Obaseki kú oríire

Buhari kí Obaseki kú oríire

Buhari kí Obaseki kú oríire

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ránṣẹ́ kú orííre sí Godwin Obaseki lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà tó wáye lónìí nípìnlẹ̀ Edo.

Obaseki tó jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fi ìdí akẹgbẹ́ rẹ̀ lábẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ize-Iyamu janlẹ̀.

Nínú àtẹjáde náà ti Garba Shehu tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí ìpolongo fọwọ́sí, ló ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn elétò ìdìbò fún bi wọ́n ṣe kéde Obaseki bí ẹni to jáwé olúbori.

Ó fí kún-un pé èyi fi kún àrídáju pé ìjọba Ààrẹ Buhari nígbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò tí kò ní kọ́núnkọ́họ nínú.

Bákan náà ló fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i pé, kó fi àṣeyọrí rẹ̀ hàn nínú oore ọ̀fẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

One comment

  1. Hope they won’t lure him back to APC

x

Check Also

Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19

Ìjọba Nàìjíríà kéde ìlànà tuntun fún ìséde Kofi-19 Ṣe àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kò sí ohun kan tó le le le tí kìí padà rọ̀, ìdí nìyí tó fí jẹ́ pé, ìrọ́jú ló yẹ ẹni tí eégún bá ń lé… Ìjọba Orílẹ̀ yìí ti fi ọjọ́ kún ìséde Kòrónáfairọ̀ọ̀sì jákèjádò Nàìjíríà. Ní báyìí, dípò aago mẹ́wàá alẹ́ sí mẹ́rin ìdájí, aago méjìlá òru sí mẹ́rin ìdájí ni Ìṣéde yóó fi má a wà. Ọgbọ̀nọ́njọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2020 ni ...