Home / Àṣà Oòduà / E Sora! FRSC ti kede oju ona to lewu n’Ijebu

E Sora! FRSC ti kede oju ona to lewu n’Ijebu

Orisun iwe Iroyin: Lati Ọwọ Olayemi Olatilewa

Awon eso oju ona ile Nigeria, Federal Road Safety Commission (FRSC), eka ti Ijebu Ode ti kede awon oju ona to lewu ni gbigba fun awon onimoto ni akoko poposinsin odun yii.
Oju ona ti won kede re naa ni masose Sagamu si Ore. Paapa ju lo, ogangan ibi awon afara odo Ososa, ikinni, ikeji ati iketa to wa ni Ijoba Ibile Odogbolu wa lara alaye to te Olayemi Oniroyin lowo
 
Bakan naa ni won tun menu ba afara odo Arun ati Omo, ikinni ati ikeji to wa ni agbegbe J4 to wa ni Ogbere eleyii to kale si Ijoba Ibile Ila-Oorun Ijebu nipinle Ogun.
Won ni ipo ti awon afara naa wa ko dara to fun aabo emi, won si n ro awon onimoto lati rora nigbakuugba ti won ba de awon ori afara yii.
“Lati nnkan bi odun meta seyin ni awon afara naa ti di pakute iku. Eti awon afara naa legbeegbe ni ko lagbara to lati dena moto to ba fe ja sinu odo.
Eleyii to si sokunfa iku aimoye awon eniyan ti won gba ona naa koja,” Ogbeni Isah Seidu to je FRSC Unit Commander ti Ijebu-Ode lo soro yii
Bakan naa ni Ogbeni Seidu, fi asiko yii ro ijoba apapo lati se atunse si awon oju ona naa. Ogbeni Seidu ko sai tun gba awon onimoto lamoran nipa yiyeba nipa gbigbe epo bentiro inu keegi sinu moto.
O tun fi kun un wi pe ti okan ninu awon waya oko won ba bo lara tabi to n sana, yoo dara ki won tete mojuto nitori awon nnkan bayii ma n je ki oko tete gbana ni akoko ijamba oko.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...