Home / Àṣà Oòduà / Ejìnrìn Wọ̀jọ ̀wọ̀jọ̀

Ejìnrìn Wọ̀jọ ̀wọ̀jọ̀

Ejìnrìn wọ̀jọ ̀wọ̀jọ̀
Awo Ọlọ́wọ̀ ló ṣefá fún Ọlọ́wọ̀
Eléyìí tí yóò roko roko tí yóò gbé kílìṣí tíí ṣe yèyé ajé wálé
Ìji lẹ́lẹ́ – Awo Ìji lẹ́lẹ́
Ìji lẹ̀lẹ̀ – Awo Ìji lẹ̀lẹ̀
Ẹ̀fúùfù lẹ̀lẹ̀ ní jági lọ́run gbàgede
Ará tí ń mẹmu
Ẹ yà wá – ẹ yà wá
Ẹ wá mẹmu
Ará tí ń mú ògùrọ̀

Ẹ yà wá – ẹ yà wá
Ẹ wá mu ògùrọ̀
Àtàná màná làgbàrá ẹmu ṣàn délé koko
Àwọn ẹja ní gbénú ibú
Níi wọ́n yọrí idádá idádá
Àwọn èyí dà dà dà ní ṣ’Awo aládà riri dà riri
Àwọn ayé padà lapòdì àdá dà
Òdì àdá padà ó wá dara igi lóko
Àwọn ẹyẹ ńlá nííre ibi àtimùjẹ̀
Pààrù ló fẹ́ jẹ

Ló fẹ́ mutàn
Ló lọ pàálá ògiri
Lọ rèé dákẹ́ sí
A dífá fún Ọlọ́wọ̀
Níjọ́ tí ogun Adó ń yi lọ́run gbiri gbiri
Ó wá ní a kìí mú gúnnugún bọ̀gún ilé
Eruku gbáà
Gbáà eruku
A kìí mú àkàlàmọ̀gbò bọ̀gún eréjà
Eruku gbáà

Gbáà eruku
Olóyè kò ní fi odidi ẹkùn rúbọ
Eruku gbáà
Gbáà eruku
Aládó ní kàrí ibi Awo kù sí
Wọ́n ní ó ku
Adégúnlọlá Awo wọn nílé Alára
Wọ́n lóku àwọn Ò wẹ̀ ṣàlà ṣàlà fi ohùn moòkùn ṣóde
Awo wọn lóde Ìjẹ̀sà
Wọ́n ló tún ku àwọn

Bòbó etídò tíí fara jọ ọká
Aládó wáá ní láláì lẹ́ni Láláì lẹ́nìkan
Ó ní itú bẹ́bẹ́
A ṣì mọ ṣẹlẹ́ni ewúrẹ́
Ǹjẹ́ tani ó ṣẹlẹ́ni mi
Ọ̀pẹ̀ ìwọọ lóó ṣẹlẹ́ni mi
Àgbò mọ̀mọ̀ ní ṣọkọ ìlágùtàn
Tani ó șẹlẹ́ni mi
Ọ̀pẹ̀ ìwọọ lóó ṣẹlẹ́ni mi
Àkùkọ tàngàlà ní ṣẹlẹ́ni àgbébọ̀ rẹ́kẹ́ rẹ́kẹ́

Tani ó ṣẹlẹ́ni mi
Ọ̀pẹ̀ ìwọọ lóó ṣẹlẹ́ni mi
Tẹ̀gbè Tẹ̀gbè Awo ilé Ọ̀rúnmìlà
Lo dífá fún Ọ̀rúnmìlà
Ifá ń lọ rèé tẹ ilé Adó
Yóó fi òde Ọ̀wọ̀ kẹ́yìn rẹ
Ǹjẹ́ Aládó Ẹ̀wí t’Ifá ṣẹ ẹ
Awo Àtẹ̀gbé t’Ifá ṣẹ ẹ
Alárá t’Ifá ṣẹ ná
Awo Àtẹ̀gbé t’Ifá ṣẹ ẹ

Ajerò t’Ifá ṣẹ ẹ
Awo Àtẹ̀gbé t’Ifá ṣẹ ẹ
Ọ̀ràngún ilé Ìlá
T’Awo láá ṣẹ
Awo Àtẹ̀gbé t’Ifá ṣẹ

Tí Ifá àti ti àwa Awo ni yóò maa ṣẹ o!
Ire ni o!

– Ìrẹtẹ̀ Ogbè (Ìrẹ̀ǹtegbè)

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo