Home / Àṣà Oòduà / Ìdí tí Oluwo fi kọ Olorì rẹ̀ sílẹ̀ rèé

Ìdí tí Oluwo fi kọ Olorì rẹ̀ sílẹ̀ rèé

Ìdí tí Oluwo fi kọ Olorì rẹ̀ sílẹ̀ rèé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kábíèsí Oluwo ti ìlú Ìwó, Ọba Abdulrosheed Adewale ti kọ Olorì rẹ̀ Chanel Chin sílẹ̀.

Agbẹnusọ fún Kábíèsí ọ̀hún, Alli Ibrahim fi ìdí ọ̀rọ̀ náà mulẹ fún akọ̀ròyìn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kábíèsí kò sọ ní pàtó ohun tó fa ìkọ̀sílẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ó sọ̀rọ̀ lójú òpó Instagram rẹ̀.

Ó ní wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ látàrí àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàrin wọn tí kò ṣe é yanjú.

Ọmọ kan ni Chanel bí fún Oluwo, orúkọ rẹ ni Odùduwà.

Olorì Chanel Chin jẹ́ ọmọ orilẹ-edee Jamaica, bàbá rẹ̀ sì ni olórin tàkasúfe é tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí “Bobo Zaro.”

About ayangalu