Home / Àṣà Oòduà / Odù kan gorí àtẹ,Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 goróyè Àràbà nílẹ̀ẹ̀bàdàn

Odù kan gorí àtẹ,Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 goróyè Àràbà nílẹ̀ẹ̀bàdàn

Odù kan gorí àtẹ,Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 goróyè Àràbà nílẹ̀ẹ̀bàdàn

Onírúurú aṣọ lára alágẹmọ, onírúurú ètè lápèjẹ sààráà lọ́jọ́ tí orí mádé, w nu agogo idẹ ní tií wà, ọrùn w’ọnú lèjígbà ìlẹ̀kẹ̀, àní lọ́jọ́ tó mú ìbàdì Àràbà Ògbó awo ,Oloye Ifalere Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 wọ Mọ́sàajì,aṣọ ọba tó taná yanran yanran .

Ko sí agbe kọrọ wí mọ́ pé, Àràbà Ògbó awo ,Oloye Ifalere Ọdẹ́gbèmí Ọdẹ́gbolá11 ni Àràbà Ìbàdàn karùndínlọ́gbọ̀n báyìí (25) àti pé òun tún fẹ́ẹ́ ẹ̀ ni Àràbà tó kéré jùlọ lọ́jọ́ orí tí ó fi dé ipò yí .

A bíi ní ọjọ́ kẹfà , oṣù kẹfà ọdún 1960. Ó bẹ̀rẹ̀ àkàsọ̀ oyè awo lọ́dún 1992, ó sì sún kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ láti ọdún náà kí ó tó di Àràbà ní ọjọ́kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2019.Èyí fihàn pé ìrìn àjò náà gbà á ní ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n kó tó goróyè.


Ìgbà yí ló sì di ọgbọ̀n ọdún àti oṣù mẹ́wàá tí bàbá a rẹ̀, Àgbà Oyè Ọdẹ́wùmì Àlàó Ọdẹ́gbolá1 fi ipò náà sílẹ̀ . Ayẹyẹ ìwúyè náà larinrin fún onírúurú àmúyẹ àṣà ìbílẹ̀ débi i pé àwọn ọlọ́dẹ ìbílẹ̀ pitú táwọn onísàngó, ọlọjẹ, ọlọya náà ò jẹ́ kí iná àṣà o kú.
(àfikún ìròyìn)

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá

Looking at the Odù, Ìwòrì bogbè cast for today’s Òsè Ifá, it could be said that sometimes our detractors feel they are hurting us but they don’t know they are pushing us to wealth. Just listen to this stanza from the Odù. Òtééré ilè ńyóÒtèèrè ilè ńyòIlè ńyó ará iwájúÈrò èyìn e kíyèsí ílèAdífá fún Ìwòrì tí yóó tarí Ogbè sínù àbàtàbútú ajéKòìpé kòìjìnà, Ogbè ló wá jìn sínú ajé gbugburu Òtééré, the ground is slipperyÒtèèrè, the ground is difficult ...