Home / Àṣà Oòduà / Ọjọ́ Kẹrin oṣu Kẹ́jọ ni ìdánwò WAEC yóò bẹ̀rẹ̀ – Mínísítà ètò ẹ̀kọ́

Ọjọ́ Kẹrin oṣu Kẹ́jọ ni ìdánwò WAEC yóò bẹ̀rẹ̀ – Mínísítà ètò ẹ̀kọ́

Ọjọ́ Kẹrin oṣu Kẹ́jọ ni ìdánwò WAEC yóò bẹ̀rẹ̀ – Mínísítà ètò ẹ̀kọ́

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé ìdánwò àṣeparí ní iléèwé girama, WAEC, yóó bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrin oṣù Kẹjọ ọdún
Mínísítà ètò ẹ̀kọ́, Emeka Nwajiuba ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́yá Ìjọba àpapọ̀ ń jábọ̀ ibi iṣẹ́ dé dúró lórí ọ̀rọ̀ Kofi-19 ní Nàìjíríà.

Ó ní “A ti ṣe ìwọ̀n tí a lè ṣe pẹ̀lú àjọ WAEC, a wá ń fi àkókò yí sọ fún un yín pé ìdánwò náà yóó bẹ̀rẹ̀ lati ọjọ́ kẹrin oṣù Kẹjọ títí di ọjọ́ karùn ún oṣù kẹsàn án ọdún 2020.”

Nwajiuba sọ pé ààyè oṣù kan wà fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ìpínlẹ̀ tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ṣiṣe idanwo naa lati pese àwọn ile ẹ̀kọ́ wọn sílẹ̀ fún ìdánwò ọ̀hún.

Mínísítà náà sọ pé iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ yóó pèsè àtẹ̀jáde àwọn àkókò tí ìdánwò ọ̀hún yóó wáyé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú àjọ NCDC, ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́, NUT, àtàwọn àjọ míràn tí ọ̀rọ̀ kan.

Nwajiuba sọ pé ìdánwò NECO àti NABTEB yóó bẹ̀rẹ̀ ní kété Lẹ́yìn ti wọn ba ti pari idanwo WAEC ọhun.

Ọdún1952 ni wọ́n gbé ìdánwò WAEC kalẹ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láwọn orílẹ̀-èdè ìwọ-oorun ilẹ̀ Áfírìkà tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́ṣì.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu