Home / Àṣà Oòduà / Ebenezer Obey ò kú o–Asojú ẹgbẹ́ Obey

Ebenezer Obey ò kú o–Asojú ẹgbẹ́ Obey

Ebenezer Obey ò kú o–Asojú ẹgbẹ́ Obey

Ó dà bí ẹni pé àwọn èèyàn kìí fẹ́ rán aṣọ wọn níbi tó gbé ya mọ́ lóde òní. Ìtọ pinpin àti àríwísí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ló kù tí wọ́n ń mójútó, bọ̀kílẹ̀ èyí sì ń dá ìṣòro tó pọ̀ sí àwùjọ, dípò o kí ó mú ìlọsíwájú báwa.

Irúfẹ́ àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí aṣojú ẹgbẹ́ orin bàbá Ebenezer Obey, Túnjí Ọdúǹbákú o bọ́ síta sọ fún akọròyìn pé irọ́ ni ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri pé gbajúgbajà olórin náà ti dágbére fáyé, kí àwọn èèyàn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà.

Ṣaájú ni ìròyìn kan gbòde lórí ayélujára pé agbaọjẹ olórin juju ọ̀hún ti gbẹ́mìí mì nílé ìwòsàn kan ní ìlú Lọ́ńdọ́nù.

Ṣùgbọ́n Odunbaku sọ fún akọròyìn pé kò sí òtítọ nínú ìròyìn náà.

Ó ní “Nǹkan bíi Ìṣẹ́jú márùn ún ṣẹ̀yìn ní mo ṣẹṣẹ bá bàbá sọ̀rọ̀ lórí awuyewuye pé wọ́n papòdà, ṣùgbọ́n kò sí nǹkan kan tó ṣe bàbá, àlàáfíà ni wọ́n wà.”

Ó tẹ̀síwájú pé irọ́ ni pé Ebenezer Obey wà ní ìlú òyìnbó.

Ọdúǹbákú parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìlú Èkó ni bàbá wà lásìkò tí òun ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, àti pé kokoko lara rẹ̀ le.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

Alhaja

Ààrẹ Tinubu ti yan Alhaja Ero Arike sí ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Àwọn Oníròyìn Tuntun tó máa kópa nínú ìpolongo rẹ̀ fún ìdìbò Ààrẹ ọdún 2027.

Ààrẹ Tinubu ti yan Alhaja Ero Arike sí ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀ Àwọn Oníròyìn Tuntun(New Media Committee) tó máa kópa nínú ìpolongo rẹ̀ fún ìdìbò Ààrẹ ọdún 2027. Ká ma purọ́, Obìnrin náà ń gbìyànjúTó bá jẹ́ pé ẹni tó bá gbé APC sí orí bíi gala wọ́n ń wá, Alhaja Ero Arike náà ti gbé e sí orí, kó sì fẹ́ràn láti sọ̀kalẹ̀ rárá Ó ti ń ṣe ohun tí ó lè ṣe láti gbé ìjọba àti ẹgbẹ́ APC lárugẹ lórí ...