Home / Àṣà Oòduà / Wọ́n ti yan adarí tuntun fún Ifásitì “Unilag”

Wọ́n ti yan adarí tuntun fún Ifásitì “Unilag”


Ó jọ bíi ẹni pé kángun kàngùn kángun ilé ẹ̀kọ́ Ifásitì ìpínlẹ̀ Èkó tí kángun síbi kan báyìí o, bí Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ṣe ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn aláṣẹ Ilé ẹ̀kọ́ gíga Ifásitì Èkó, Unilag ti yan Gííwá tuntun míì láti máa tukọ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Folashade Ogunsola ló gbégbá orókè nínú gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn, èyí tó wáyé láàrin àwọn Ilé ìgbìmọ aṣòfin Ifásitì náà tí wọ́n fi yan adelé.

Folashade ni ìgbákejì ẹ̀ka ìdàgbàsókè fún Gííwá tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, Oluwatoyin Ogundipe.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, nínú ìbò mẹ́tàdínláàdọ́ṣàn, Folashade nìkan ní ìbò márùnléláàdóje.

Ẹnìkejì tí wọ́n tún fojú sùn fún ipò kan náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ben Ogbojafor ní tirẹ̀ ní ìbò mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

Níbi ìpàdé ìjókòó ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin Ifásitì náà tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ni wọ́n ti yan Folashade.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu