Home / Àṣà Oòduà / A o ni ri ogun aisan

A o ni ri ogun aisan

A o ni r’ogun aisan!
Ifa ni:
Pere ni tewe iyeye, aloye ni ti peregun;
Piri l’eye olongo n ji;
A kii b’okunrun eye lori ite;
Gege lowu alantakun n fuye;
Ota kii ku, ota kii run;
Koko lara ota n le;
Ojojo kii sokuta lale odo;
Aluti la n lu eru oko;
Aluti la n lu eru ada;
Ere kii ba eri wo;
Ko ba won wa kii ba won lo;
Ope kii ba igi oko wo’we;
Efun kii mu igun, edi kii mu alakan;
Ota t’ota pa ka sai segun ota fun wa!
Aase!
Ao ni ba won ku iku ajoku!
Edi, efun, asasi ko ni mu wa ati awon tiwa!
Aaaaaaaaaaaase.

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...