Home / Àṣà Oòduà / Adúmáadán Àjèjé

Adúmáadán Àjèjé


Ẹmu daada ní ń bẹ nínú ahá
Ògùrọ̀ àtàtà ní ń bẹ nílẹ̀ akèrèǹgbè
Ọtí ò dá, àlejò ò lọ!
Ẹni ọtí kìí tí Adúmáadán
Adúmáadán Àjèjé
má gbádùn ara rẹ lọ!

‘Òògùn ibà ni, òògùn ibà ni,’
Bí eré, bí eré ìyálé ilé mútí yó!
Ẹmu lásán ni kìí pàayàn
Àṣẹ̀yínwá àṣẹ̀yìnbọ̀ baálé ń tọ̀ sí ṣòkòtò.
Akúwárápá abitọ́ funfun lẹ́nu.
Èpè akèǹgbè ọmọ a jà lóòjọ́.

Orin:
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Bó ṣegbá kan bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Bó sì ṣèjì n ò kọ̀ bùn mí lẹ́mu- bùn mí
Sá ti bùn mí lẹ́mu- bùn mí.

Adúmáadán Àjèjé ìfẹ́ rẹ ń pá mí lọ!
Adúmáadán ọmọ dúdú bí i kóró iṣin
Adúmáadán jọ̀wọ́ arẹwà eèyàn!
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu- bùn mí Adúmáadán jẹ́ n rẹ̀ǹgbẹ ìfẹ́.
Adúmáadán má lókùú èèyàn lọ́rùn!
Adúmáadán bùn mí lẹ́mu ìfẹ́ mu jọ̀wọ́ jàre!
Àdúmáadán mo fẹ́ ká jọ ma mẹ́mu ìfẹ́ pọ̀!
©#Ká_rìn_ká_pọ̀

About ayangalu

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo