Home / Àṣà Oòduà / Ajimobi àti Yinka Ayefele pàdé níbi ayeye Àádòrún odún (90) ojó-ìbí Olúbàdàn.

Ajimobi àti Yinka Ayefele pàdé níbi ayeye Àádòrún odún (90) ojó-ìbí Olúbàdàn.

Ajimobi àti Yinka Ayefele pàdé níbi ayeye Àádòrún odún (90) ojó-ìbí Olúbàdàn.
Ìyàlénu ñlá gbáà ni ayeye Àádòrún ojó-ìbí olúbàdàn ti ilè ìbàdàn tí a mò sí Oba Saliu Akanmu Adetunji ní ojó Àìkú.
Gómìnà ìjoba ìpínlè Oyo Abiola Ajimobi lo síbi ayeye Àádòrún odún ojó-ìbí Olúbàdàn tí ìyàwó rè sìn ín lo, ìyàwó rè tí a mò sí Mrs. Florence Ajimobi, Gómìnà ìpínlè Oyo télè náà lo èyun-ùn Adebayo Alao-Akala; Teslim Folarin náà kò gbéyìn àwon míràn náà sì péjú síbè.
Gbajúgbajà olórin Yinka Ayefele náa lo síbi ayeye ojó-ìbí náà tí ó sì hàn wípé inú rè ñ dùn gan kòdá nígbá tí ó rí Ajimobi inú rè tún dùn gan, èyí hàn ní ojú rè púpò bí ó tilè jé wípé won sèsè wó ilé-isé rè tí ó rún owó ribiribi sí ni tí òpò sì ba kédùn .
Ayeye tí ó wú ni lórí yîí ni Oònirìsà, Oba Adeyeye Enitan tún lo síbè náà tí àwon oba míràn náà sì péjú síbè bíi Oba Eleruwa ti Èrúwà, Oba Samuel Adegbola; Olugbo ti Igbo; Oba Obateru Akinrintan àti Obanikoro láti èkó, tí ó wá sojú Oba Èkó, Oba Rilwan Akinolu.

About Awo

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo