Kàyéfì nlá ni ó jé nígbà tí Arákùnrin kan ya wèrè ní ìlú Benin ní ìpínlè Edo.
Gégé bí ìròyìn se so, òdókùnrin yí ni won fi èsùn kàn wípé isé kí á máa fi èro gbáni ni ó n se tí a mò sí Yahoo ni ó n se.
Nígbá tí ó ya sòkòtò pénpé mó ara rè tí ó sì jókòó sí ilè’lè ní ìta gbangba, tí ó sì n jéwó àwon ìwà ìbàjé kan.
Ìsèlè náa selè ní Agbior park by Ohovbe junction ní ìlú náa tí ó sì fa òpò èrò tí àwon ará àdúgbò sì fi se yèyé wípé àwon mòó dáadáa.
Won fi èsùn kàn wípé ó ra okò tuntun fún bàbá rè kí ó tó di wípé ó kú, won so wípé ó n kà wípé òun ti fi òpò ènìyàn se ògùn owó.
Nibi fídíò ti a rí wò nse ni arákùnrin yí n pariwo “Daddy, Daddy” nígbà tí ó fi ara rè se èsí ní ìta gbangba tí àwon èyàn sì ni kí ó máa jèrè isé owó rè.
Tagged with: Àṣà Yorùbá