Home / Àṣà Oòduà / Atelewo ni mo bala

Atelewo ni mo bala

Ki n to so die fun yin lara itan igbesi aye mi kan ti mi o le gbagbe laelae. Se e ko gbagbe alaye ti mo se fun yin lose to koja? Lara ona ti eniyan le fi se se awari talenti to ni ni nipa sise akiyesi si awon ohun ti okan eni n fa si ju lo, awon ohun ti maa n dani lorun bi egbin, awon nnkan ti maa n fun ni nisipaya, iwuri tabi koriya, itara tabi awon nnkan ti maa mu ara eni bu maso lopo igba. Awon ohun to jeni logun julo ati ohun to maa n wu ni i se tun je apeere pataki ti a ko gbodo foju pare.

Ilu Ibadan ni won bi mi si, ibe naa ni mo si dagba si. Ileewe Jericho High School to wa ni Eleyele niluu Ibadan naa ni mo ti ka iwe mewaa mi pe lodindi. Ni awon akoko ti mo wa ni ileewe girama, mo nife iran ere boolu wiwo pupo to fi je wi pe mo fi aseju kun-un. Ti won ba na Super Eagles mi o ki n le jeun, inu mi a baje bi eni ofo se, omi ekun yoo si maa da loju mi poroporo. Aimoye igba ni mo maa n sa kuro nileewe lati lo woran ere boolu Shooting Stars ni papa-isere Lekan Salami to wa l’Adamasingba, ni awon akoko ti ere boolu liigi Naijiria ba bo si aarin ose. Bakan naa, ko si ere boolu ti won gba ni awon ilu okeere bi liigi Premier ti ko ye mi yekeyeke.

Ife boolu yii wo mi lokan to bee gee to je wi pe mo bere si ni ri ara mi gege bi agbaboolu. Yato si awon boolu alagbole ti mo ti n gba tele. Mo pinnu lati darapo mo egbe agbaboolu kan ti won maa n sedaraya ninu ileewe Oba Akinbiyi High School to wa loju ona Mokola-Oremeji. Mo ti bere si n ri ara mi gege bi okan lara awon agbaboolu ile okeere nla. Mo n ro wi pe laipe ni irawo mi yoo yo loke, maa si dapesin kari aye. Awon eniyan yoo maa pon mi le, maa lowo bi elewu etu, maa si ra moto jo bi isu.

Leyin ose kan ti mo bere, o ti bere si ni su mi, o ti n re mi. Ko kuku je wi pe boya ni mo ti moo gba, mo kan an tiraka naa ni. Yato si eleyii, ohun ti mo lero ko ni mo ba. Inira gbaa lo je fun mi, mo tiraka lati lo lose keji. Sugbon ose keta re ni won o ri mi mo.

Leyinoreyin lo ye mi kedere wi pe boolu gbigba ki i se ebun mi. Oju kokoro lo sun mi debe. Owo, okiki, iyi ati ogo to ro mo awon irawo agbaboolu gan-an lo je ki boolu wu mi gba. Eleyii to si je asise ti opolopo n se laye ode oni.

Boya ki n tun beere ibeere naa leekansi: kin ni awon ohun ti e maa n fe lati se bi won ko tile ni fun yin ni kobo nidi re? Idahun ibeere yii lo le se afihan ojulowo ebun te e ni.

Afikun, ohun naa gbodo je ohun ti yoo ro yin lorun ni sise. Bi o tile nira fun awon kan, awon ti won lebun naa ko ni ri bi inira rara. Maa duro nibi, sugbon mi o ti pari alaye mi. O di gba.

http://www.olayemioniroyin.com/2015/11/atelewo-ni-mo-bala-2.html

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo