Ó yá,
Ẹ jẹ́ á sàm̀bátá àwọn jagunjagun wa.
Ẹ jẹ́ ká f’orin ọgbọ́n yẹ̀ wọ́n wò,
Ká mọ rírì isẹ́ wọn t’ó yakin.
Pàtàkì l’àwọn ológun lórílẹ̀-èdè yìí;
Ișẹ́ takuntakun ni wọ́n kúkú ń ṣe.
Mo kírà f’áwọn sójà káàfàtà.
T’ọ̀sán t’ààjìn n’ọ́n ń șișẹ́ ìlú.
Bẹ́ẹ̀ ni tẹ̀mítẹ̀mí ni wọ́n fi ń jagun.
Bá a bá gúnyán wọn tán,
Ká f’ewé bò ó ló tọ̀nà.
Géńdé tó tó géńdé ní í lọ s’ójú-ogun.
Okùnrin tó t’ọ́kùnrin ní ń șișẹ́ẹ sójà,
Ẹni ẹ bá rí ẹ bi.
Akọni ogun ni wọ́n;
Kútańtì ni wọ́n-ọ́n ṣe.
Ìbà ẹ̀yin arógunmásàá;
Ọmọ arógun-má-fìgbà-kan-șojo.
Mo gbé’dìí f’ẹ́yin arógunyọ̀șẹ̀șẹ̀ káàfàtà.
Bí wọ́n ti ń pa wọ́n tó;
Bẹ́ẹ̀ l’eegun wọn ń le kankan bí iwin.
Wọ́n ń pebi mọ́nú ń’torí Nàìjíríà;
Wọ́n ń fara gbọta nítorí àwọn ọmọ wa.
Síbẹ̀, Zambo Dàsúkì,
Àt’àwọn ajòdìjẹ̀sọ̀ bíi tiẹ̀,
Wọ́n f’owóo wọn dá wọn lára.
Wọ́n f’ohun-ìjà dùn wọ́n;
Wọ́n f’ẹ̀mí wọn șòfò púpọ̀.
Bí wọn ‘ò mú Dàsúkì láyé,
Olódùmarè á mú alákọruwo.
Òbìtà ènìyàn tó sọ omi ọkà d’omi ìwẹ̀.
Ká sọ ọ́ kó yé wa yéké.
Àìsí nǹkan-ìjà tó gúnmọ́,
Lokùnfà bí Boko Haram ṣe ń rí wọn pa.
Ohun ojúu wọn ń rí kèrémí kọ́.
Nítorí ìșọ̀kan Nàìjíríà.
Ojoojúmọ́ l’àwọn sójà ń kú.
Ẹgbẹ̀ta la tún pàdánù láìpẹ́ jọjọ;
Tí gbogbo ẹbí wọn șì ń șọ̀fọ̀.
Àláùrà bá wa forí jì wọ́n o.
Șíjú àánú wò wọ́n,
Gb’ójú nínú ișẹ́-ibii wọn.
Kẹ́ wọn, gẹ̀ wọ́n.
Jẹ́ kí wọn ó r’Álùjánnà wọ̀.
Àwọn sójà t’ó kù láyé,
Pàápàá àwọn t’ó wà lójú ogun.
Bẹ̀rẹ̀ lát’orí ìmùlẹ̀ mi Adérẹ̀mí.
Tó fi káríi wọn gbogbo pátá poo.
Ọba-òkè bá wa mú wọn padà wálé.
Kí wọn ó ṣẹ́gun àwọn oníjàádì.
Alóyúnmábíi ọmọ ọba Kétu.
Awàșẹẹ̀tùdànù l’awo Awùjalẹ̀.
Bí wọ́n bá nàbọn sí wọn,
Kò ní f’ọhùn òkè.
Ẹ ‘ò ní ṣe kòńgẹ́ àgbá.
Ẹ ‘ò ní kú’kú àpalàdọ̀ fáàbàdà.
Apáa Boko Haram ‘ò ní káa yín.
Nítorí apá awọ́nrínwọ́n kì í ká’gi oko.
Apá àtẹ́lẹsẹ̀ kì í ká’jú-ọ̀nà.
Magbẹ̀yìn magbẹ̀yìn l’àgbà Lédì ń ké.
Kẹ́ ẹ rẹ́yìn ogun ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn.
Àmín àṣẹ!