Home / Àṣà Oòduà / Awon igbimo Olubadan foju Seriki gbole ni kootu

Awon igbimo Olubadan foju Seriki gbole ni kootu

*Won ti dajo iwuye Adetunji gege bi Olubadan tuntun

Gege bi oro awon Yoruba to wi pe, ti oba kan ko ba ku, oba mi ki i je. Eleyii ni awon igbimo Olubadan tile Ibadan tele pelu bi won se da ojo tuntun ti won yoo fi oba tuntun je leyin ipapoda Oba Samuel Odulana Odugade to waja lojo kokandinlogun osu kinni odun yii (19/01/16).

Nibayii, gbogbo eto ti to, ojo kerin osu keta odun yii (04/03/16) ni won da lati jawe oye Oba Olubadan le Oloye Saliu Akanmu Adetunji lori gege bi Olubadan tuntun.

Igbese tuntun yii lo waye leyin ti ile ejo da Oloye Adebayo Oyediji lebi lori ipejo to gbe si iwaju ile ejo lati da eto ifinijoye naa duro. Saaju akoko yii ni idile seriki ti Oloye Oyediji n se olori fun gba iwaju adajo Mukhtar Abimbola lo pelu esun wi pe, awon igbimo olubadan ko leto lati fi oba tuntun je nigba ti ejo si wa lori eni to ye lati joba ni kootu. Sebi won ni tigi ba relugi, toke re la a ko re kuro.

Awuyewuye ti won te pepe re siwaju ile ejo naa ni eyi  ti olori idile seriki, Oloye Oyediji, ti n so wi pe, oun loye lati je Oba Olubadan. Ejo naa si ti de ile ejo eleyii ti ko ti niyanju titi di asiko yii. Sugbon ni akoko ti eyi n lo lowo, ni awon igbimo Olubadan n so wi pe, jije oye Olubadan ko ruju, “Balogun Olubadan ti n se Oloye Saliu lokan lati joba. Kosi si ohunkohun to le di wa lowo lati ma se ohun to ye. Eni ti inu re ko ba dun si i le gbejo lo si kootu ijoba,” awon igbimo fenu ko bee.

Sugbon sa, gbogbo atotonu amofin-agbejoro Abideen Adeniran ti n soju idile seriki lati ma je ki eto oba jije naa waye lo ja si pabo nigba ti adajo agba ti n joko nile ejo to gaju nile Ibadan, Onidajo Mukhtar Abimbola da ejo naa nu gege bi ejo ti ko lese nile rara.

 

http://www.olayemioniroyin.com/2016/02/awon-igbimo-olubadan-foju-seriki-gbole.html

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo