Home / Àṣà Oòduà / “Awon irinse ti a n lo ti darugbo”- Oga panapana ilu Eko

“Awon irinse ti a n lo ti darugbo”- Oga panapana ilu Eko

Oga agba ileese panapana ti ijoba apapo, Federal Fire Service, eka ti ipinle Eko, Ogbeni Aderemi Olusola Theophilus ti sapejuwe ikiyesara gege bi ogun-ajisa lati dena ijamba ina abaadi. Ninu oro re, eleyii to so lori telifisan ipinle Eko, o ni ona to ya ju lati yago fun ijamba ina ni ki awon eniyan sora fun awon eroja to le tete gbanaje.

Ogbeni Aderemi tun so siwaju wi pe, ona lati dena ijamba ina ko yo awon obirin ile sile nipa akiyesi to peye nigba ti won ba n dana ninu ile. Bakan naa lo tun fi kun un wi pe, ki awon eniyan maa ri daju wi pe gbogbo ohun elo ile ti n lo monamona ni won pa nigba ti won ba fe jade. Ko sai gba awon awako oju popona lamoran lati yago fun iwa gbigbe epo sinu keegi ninu oko. O ni awon nnkan wonyii le sokunfa ijamba ina ojiji.

Bakan naa, Ogbeni Aderemi ko sai menu ba ipo ti awon irinse ile ise panapana ijoba apapo tilu Eko wa.

“Ohun to daju ni wi pe, ise wa ko le rorun lai ni awon irinse igbalode to je ojulowo. Pupo ninu awon irinse wa ti a n lo ni won ti dogbo; gbogbo igba ni won baje nitori igba ti lo lori won. Ko ba dara ti ijoba apapo ba le se iranwo nipase rira awon irinse ati oko tuntun eleyii ti yoo ran wa lowo lati daabo bo dukia ati emi awon ara ilu lapapo,” Ogbeni Aderemi fi kun oro re bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo