Home / Àṣà Oòduà / Awon olokada rogo lowo olopaa ilu Ibadan: Won ni ese nla ni lati gbero meji seyin.

Awon olokada rogo lowo olopaa ilu Ibadan: Won ni ese nla ni lati gbero meji seyin.

Orisun
Awon olokada rogo lowo olopaa ilu Ibadan: Won ni ese nla ni lati gbero meji seyin. Olayemi Olatilewa

Awon olopaa ilu Ibadan ti bere si ni mu awon olokada ti won ba ti ko ju ero kan lo seyin loju popona ilu naa.

Igbese yii lo tele atejade eleyii ti alarinna ile ise olopaa ipinle Oyo, Adekunle Ajisebutu (DSP) fi sita. Ninu atejade yii lo ti so gbangba gbangba wi pe ese nla ni bayii fun olokada igboro ilu Ibadan lati ni ju ero kan leyin lo, yala okada adani tabi eyi ti won fi n pawo.

Ogbeni Ajisebutu ko sai menu ba idi pataki ti ile ise olopaa fi gbe igbese tuntun yii.

Lara oro re, o ni owo ile ise olopaa ipinle naa te isowo awon ole kan to je wi pe okada ni won fi n sise ibi.

Idi ni yii ti ile ise olopaa fi gbe igbese tuntun yii. Eleyii ti won lero wi pe yoo mu adiku ba ole jija nipa lilo okada.

Iwe Iroyin Owuro ba Ogbeni Ajadi, okan lara awon olokada ilu Ibadan, eni ti gbogbo eniyan mo si Yalumo, soro lori igbese tuntun ti ile ise olopaa gun le.

“Emi o ro wi pe igbese naa le mu adiku ba ole jija ti won fi okada se. Nitori wi pe pupo awon ole yii maa n ni ju okada kan lo. Eleyii ti yoo rorun fun won lati gbe enikan seyin, ti won yoo si sise ibi owo won. Awa olokada ni won kan fe fiya je nipa ofin tuntun naa”. Ogbeni Ajadi n na agbegbe Gate si Gbagi Alakia to wa ni ilu Ibadan.

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo