Home / Àṣà Oòduà / Yinka Ayefele sodun fun awon alaini ati omowewe

Yinka Ayefele sodun fun awon alaini ati omowewe

Aimoye awon omo wewe ni won pejo si bi ayeye odun keresimesi ati babakeresi ti ile ise redio Fesh FM ti Yinka Ayefele eleyii to waye ni Music House, ile orin Ayefele, to kale siluu Ibadan. Asekagba naa lo waye ni ojo kerinlelogun osu kejila odun (24/12/15) nibi ti awon omowewe ti gba aimoye ebun rele.

Leyin ajoyo pelu awon omode ni Yinka Ayefele, eni ti aare ana, Goodluck Jonathan, fi ami-eye M.O.N dalola tun gun ori redio re lo lati pin ebun odun fun awon opo ti ko loko lori afefe. Lori redio naa ni Yinka ti kede wi pe, awon opo bi aadota ti won ba pe sori redio naa yoo gba ebun keresimesi eleyii ti yoo mu odun won dun pelu egberun marun-un owo naira.

Gege bi oro oludamoran nipa eto iroyin fun Yinka Ayefele, David Ajiboye, se so, o ni asekagba ayeye to waye l’Ojobo to koja yii lo ti beere bi ose bi meloo kan seyin nibi ti awon omowewe lati orisiirisii ileewe ti n ya wa lati wa yo ayo keresimesi pelu Ayefele.

Siwaju sii, Yinka Ayefele, omo bibi Ipoti-Ekiti, tun fi asiko naa ranse ikini odun si awon ololufe re.
“Mo n fi asiko yii ki awon ololufe, ore ati awon ebi mi ku odun. Paapa julo, awon eniyan ti won lowo ninu aseyori mi laye. E ku odun. O dun ayabo fun wa o. Amin,” Ayefele ranse ikini re bee.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí

Ìrọ̀rùn dé, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ le è dúró kọrin báyìí Ẹ̀dá tí tó bá sì wà lókè èèpẹ̀ tó ń ṣẹ̀mí, ìrètí kò pin fúnrúfẹ́ onítọ̀ùn, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún gbajúgbajà olórin jùjú n-nì, Yínká Ayéfẹ́lẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ó ti le è nàró báyìí lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ tó bá wù ú. Èyí kò ṣẹ̀yìn kẹ̀ẹ̀kẹ́ ìgbàlódé kan tó ní àwọn èròjà ìrọ̀rùn tó ṣe é yí sí ọ̀tún àti òsì, òkè àti ilẹ̀, ibi tó bá sì ...