Lara awon iroyin wa to ti jade tele, awon iroyin lori ate Olayemi Oniroyin, mo se lalaye wi pe Edua Oke ko da ile Adulawo gege bi ibugbe awon otosi ati alaini; awon olori wa lo so ilu wa di ero eyin ati akurete.
Olorun fun wa ni awon eniyan olopolo pipe, sugbon kaka ki won ri iranlowo nipa ironilagbara, pupo iru awon eniyan bee di eni itanu lai ni oluranlowo kankan.
Tuntun mii ti jade: Olayemi Oniroyin tun ti gbo nipa omode onise opolo nla kan ni orileede Uganda ti ile Adulawo.
Omokunrin kekere yii lo dara nla yii lati Mubende to wa ni orileede Uganda. Gbogbo awon ara abule ibi ti omo naa n gbe nise owo re ya won lenu pupo ju.
Omo kekere yii to igi papo, o fi se oko bogini pelu ero ayarabiasa.
Olayemi Oniroyin, mo ti n rise ona (art) to fakiki, eleyii tun jo mi loju.
Ki Olorun ba wa da omo naa si, ki Edua oke si ba wa ran oluranlowo si i.
Olayemi Oniroyin ni oruko mi, ilu Naijeria olokiki ni mo n gbe. Mo feran iyan pelu obe egusi ti won ko eran ogunfe le lori.
Emi kii mu oti lile o, sugbon ti mo ba ri Chivita to tutu, mo le maneeji re.
E ku faaji opin ose!