Home / Àṣà Oòduà / Ebola seruba awon eniyan niluu Calabar

Ebola seruba awon eniyan niluu Calabar

O kere tan, awon eniyan bi mewaa ni won ti se ayewo fun bayii niluu Calabar latari wi pe won ni ibapade pelu okunrin kan ti won fura si wi pe oseese ko ni arun Ebola.

Okunrun ti won fura si yii lo ku nikete ti won da dubule ni ile iwosan kan to wa niluu Calabar. Bi o tile je wi pe ko si aridaju wi pe ebola lo seku pa okunrin naa, sugbon awon apere ti won ri foju han wi pe oseese ko je Ebola.

Idi niyii ti won fi bere ayewo fun awon noosi ti won toju re ati awon eniyan mi-in to ni ibapade pelu oloogbe naa.

Leyinoreyin, “negetiifu” ni ayewo ti won se fun won gbe kari. Eleyii to tun mo si wi pe won ko ni arun naa lara.

Lojo Wesde to koja yii (07/10/15), orileede bi Guinea, Sierra Leone ati Liberia yo ayo odiindi ose kan lai gburo ebola eleyii to ti n finna mo won labe aso lati inu osu keta odun 2014.

O le ni egberun mokanla (11,000) eniyan ti ebola ran lo sorun ni apa iwo-oorun Afirika. Isele ebola yii lo si fe e je eyi to se ijamba ju lo ninu itan ajakale arun.

Ebola gbori wole si orileede Naijiria losu keje odun 2014 nigba ti okunrin onisowo kan, omo ilu Liberia sadeede subu lule logido ni papako ofurufu to wa l’ Eko oba Akiolu.

Nipase akitiyan ijoba ipinle Eko, orileede Naijiria segun ebola leyin to gbe eniyan meje mi, eleyii to je iye eniyan to kere ju lo ni awon ilu ti ebola ti sejamba.

 

Orisun: Olayemioniroyin.com

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*