Home / Àṣà Oòduà / Eeto Owe L’esin Oro

Eeto Owe L’esin Oro

YAKUB BUKKY –
Nje a tun ti de loni gegebi ise wa ni gbogbo ojoru. Oro enikokan wa koni dojuru oo (amin), a ki gbogbo kaabo si akootun eeto yin, eeto wa owe l’esin oro, oro l’esin owe, ti oro ba sonu, owe la fi n wa. N o ni salai se iba fun Olorun ti o funwa ni oore ofe nla lati tun fi pade ni ose yii, moki kabiyesi olumoye ti ilumoye akoko, moki yeyeoba, gbogbo ogbimo aafin, awon oloye, mio gbagbe awon oloori laafin naa ati gbogbo omoba l’okunrin ati l’obinrin wipe a tun kaabo si ori eeto loni.
Gegebi isee wa, lori eeto yii ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan ati lilo won ninu oro, e wa nkan fidile, ki e maa bawa kalo.

Owe akoko ti a o maa gbe yewo lo bayii: IMADO IBA SEBI ELEDE A BA ILU JE, ERU I BA J’OBA, EYAN I BA TI KU IKAN.
ITUMO/ LILO; imado je elede igbo, ti o le ju aja lo, o buru ju elede ile lo, koni suuru bi elede ile. Meji meji ni Olorun n da nnkan, o fi eyi ti o dara sinu ile, o fi eyi ti o lewu sinu igbo. Fun apeere: aja- aja’ko, obo-inaki, ekolo-ejo, elede-imado.
Gegebi mo se so siwaju, iwa ipata, ipanle po lowo imado, ti o ba wa ni anfaani lati de ipo ola, yio s’aye je, boya ki a so wipe, a fe muwa sinu ile gegebi elede, yio ba nkan ti o dara jee. Bi elede yio ba jeun, enu ni o fi n tu ilee, je igbe ni akitan, ti a ba wo imado-elede igbo, ni bi o ba wa ni aarin eyan, eyin ni o fii n ja. Beenani, ti a ba fi eru j’oba, yio si ipo naa lo, nitoriwipe, gbogbo iya to tije nigba tio wa nipo eru, ni yio fe fi je awon eeyan pada.
A maa nlo owe yii, ti a ba ri onijagidijagan tabi onijiibiti eda, ti o n wa gbero tabi ti o n sapa lati maa dari awon eniyan, tabi lati maa se akooso nkankan.

Owe keji ti a o maa gbeyewo fun toni lo bayii: OROMADIE O MON AWODI, IYA E LO MON AASA.
Itumo/lilo; oromadie je omo adire keekeeke, ti iya won sese paa, won o gbon lati le mon ise ibi ti awodi,/aasa, eye buruku to n gbe loju orun le se, sugbon iya re mo itu ti aasa le pa, awodi ko nise meji ju ko gbe adire lo. Ti aasa ba ti yo lookan ni adire a ti maa raaga bo omo re. Awofin yii lawon eyan ri bi aasa yio se maa ja sooro bo, ti oromadie yio maa sere ni tire,. Pelu agbara, ti iya oromadie yio si maa rababa nile lati daabo nla bo awon omo re oromadie.

 

A maa nlo owe yii, ti a ba sakiyesi wipe eni ti ko nimo nipa nkankan n rin ni bebe nkan ti o le se akoba nla tabi eewu nla fun. Tabi ti maajesin kan koba mon iru eda ati iru itu ti a le pa fun oun, ti o n fi oju tembelu wa, a le pa owe yii na fun bakanna. Toooo, nibi ni a o ti sewele fun ti ooni, eyin ojogbon inu aba yii, gegebi e se mon wipe a n korawa l’eko laafin ilumoye nii, a n reti afikun, akiyesi tabi ayokuro ki o le ba je anfaani fun gbogbo wa, nitori ‘ogbon ologbon ni kii je ki a pe agba ni were’. E funwa ni awon owe ti o farape awon owe ti a ju si afefe loni, ki a tun ko imo kun imo.

E seun

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo