Home / Àṣà Oòduà / Emi ati Alao-Akala ti lepo di okan soso- Gomina Ajimobi

Emi ati Alao-Akala ti lepo di okan soso- Gomina Ajimobi

*Ajimobi fogbon juko oro si Ladoja

Leyin awuyewuye ati awon oro ti n lo nigboro nipa wi pe gomina tele fun ipinle Oyo, Christopher Alao-Akala n mura lati darapo mo egbe APC ti pada jade lenu Akala funra re bayii. Oro yii ni Alao-Akala, eni ti awon kan tun un pe ni Omo Iya Alaro, fi da awon eniyan loju nikete ti ile ejo kotemilorun pada da Ajimobi lare gege bi gomina ti o maa tesiwaju ninu isejoba  ipinle Oyo. Akala ni gbogbo eto lo ti to, oun si ti setan lati darapo mo egbe APC ti won dasile lojo kefa osu keji odun 2013.

Ninu alaye to te Olayemi Oniroyin lowo, Abiola Ajimobi to je gomina ipinle Oyo ni idarapo Alao-Akala mo egbe APC dabi igba ti alagbara meji ba gbimopo lati di okan soso. O ni igbese tuntun yii yoo so awon di erikina nla ti enikeni ko ni le da lona.

“Gomina ipinle Oyo tele je eekan nla ti ko se fowo ro seyin lagbo oselu ipinle Oyo ati ni Naijiria lapapo. Eerin nla niluu Naijiria, to ba de ilu London, eerin naa ni yoo tun maa je. Bakan naa, eerin nla ninu egbe PDP ati Labour, eerin naa ni yoo tun maa je to ba de inu egbe APC.

“Ni ojo toni, ti a ba ni ka maa so nipa awon to lenu nibe ninu oselu ipinle Oyo, a maa so nipa Ajimobi, Akala ati Ladoja. Ibasepo emi ati Akala yoo mu wa di alagbara eleyii ti enikeni ko ni le ko lona. Nigba ti akogun meji ba dokan, talo tun seku? A ko ni i lo lati daruko enikeni, awa nigi nla ti ko se e kolu.” – Ajimobi se lalaye bee.
Orisun: Olayemioniroyin.com

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo