Home / Àṣà Oòduà / Ewe Yi Je Òkan Lara Awon Ewe Ifa To Dara Pupo

Ewe Yi Je Òkan Lara Awon Ewe Ifa To Dara Pupo

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin ku isimi opin ose, emin wa yio se pupo re laye ase.
Laaro yi mofe ki a mo iwulo ewe to wa ninu aworan yi lati inu odu mimo eji elemere(irete meji), oruko ewe yi yio maa je okán, ewe yi je òkan lara awon ewe ifa to dara pupo lati fi maa we ifa wa o si tun wulo fun akose ifa lorisirisi ona, sugbon ninu odu ifa irete meji yi a maa nlo fun eniti odu ifa yi ba jade si latari Ogun amubo, aseti tabi ki won ba eniyan da majemu ki won ma fise, a maa nfi ewe yi nwe ese akapo naa mejeeji ni pelu awon ewe miran to pelu.

 
Ifa naa ki bayi wipe:
Emi ote
Iwo ote
Igbati ote di meji lo dododo a difa fun baba olorire malese ire igba iwase eleyi ti ori re nfojojumo ngbare sugbon ti ese mejeeji ko lo gba ire naa, won ni ko karale ebo ni ki o wa se nitori bi ori re ba tile gba ire ki ese re mejeeji naa baa le lo maa gba ire naa, obi meji, eyele funfun, ewe okan, ewe ire, ewe akinsan, ewe aje sefunsefun, baba kabomora o rubo won se sise ifa fun nigbakugba ti ori baba bati wa gba ire ese re mejeeji yio wa lo gba ire naa, baba wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.

 
Baba wa fiyere ohun bonu wipe:
Nje bi okan bayo ninu igbo a bona wa ire kasai wami wa o ire
Bi aba bu Omi sori a bese wa ire kasai wami wa o ire.
AKOSE IFA RE: ewe okan, ewe aje sefunsefun, ewe akinsan, ewe ire ao gbo won sinu Omi ao gbaye ifa yi si ao fiwe ese wa mejeeji ao wa fi obi meji ati eyele funfun kan bo ese wa mejeeji naa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ire gbogbo yio maa sawari wa, ese wa mejeeji koni lodi sori wa, ao segun amubo, aseti, ijakule ati ki won ba eniyan da majemu ki won ma fise o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version
Continue after the page break

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo