Home / Àṣà Oòduà / Ewi Awon Omode: E Ma Ya Baseje

Ewi Awon Omode: E Ma Ya Baseje

Ewi: E ma ya baseje

Eyin ewe iwoyii, e wa teti si agogo ogbon

E ma ya baseje

 

Baseje ti n bale je ni won pe larungun

Arungun ni eni ti n ba ohun ti won fowo se je

Oninakuna omode ni won pe lapa.

E ma ya baseje

E ma ba ohun ti won fowo ra je.

To ba je omo ile iwe toju iwe re daada

To ba wa nile ma ba ohun iya ati baba fowo ra je

Ibikibi too ba de, toju ohun gbogbo ti nbe layika re

Ti won ba fun o lowo ma nanakuna

Oninakuna won ki i rowo se ohun rere laye

Omode to ba yapa won ki i ni laari bo dola.

E ma ya baseje

Eniyan to ba ba ohun ti won fowo se je kii niyi.

Orisun: olayemioniroyin

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...