Home / Àṣà Oòduà / Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

Idile Alayo: E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Idile Alayo wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.

Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e nse lori eto yi, Eledua yoo pin yin lere o, beeni mo ki gbogbo awa ti a nda si eto yi wipe Olodumare yoo da soro aye enikookan wa o. Amin

E jowo olootu oro kan ni ko fe ye mi ti mo nilo amoran awon ojogbon le lori. Odun keji ree ti mo se igbeyawo, ti Eledua si ti fi omo kan da idile mi lola, isoro kansoso ti mo ndoju ko nile oko mi ni wipe, oko mi ti feran odi yiyan ju, afi bi ounje ni odi yiyan je fun oko mi, ohun ti o ro oko mi lorun julo ni ki oun ati eniyan ni gbolohun aso ki won si maa soro si ara won mo titi lae.

Ohun ti o wa nje edun okan mi lori oro ile yi gan ni wipe, gbogbo eni ti oko mi ba ti ba ja bayi, ni yoo fe ki emi pelu maa yan lodi, beeni emi si korira odi yiyan pupo, koda mo se akiesi wipe, Eleda mi ko feran odi yiyan rara, tori gbogbo igba ti mo ba ti n yan odi ni nkan kii lo dede fun mi mo, koda kii je ki n ri orun sun bi o ti ye. Beeni oko mi yoo si maa pon dandan re fun mi wipe, gbogbo eni ti o ba ti je ota oun, ni o gbudo je ota mi, beeni awon ore oun pelu si gbudo je ore mi.

Ko si rorun fun mi rara lati tele ofin yi. Gbogbo awon ayalegbe egbe wa ti a jo wa ninu ile kan na, ni oko mi kii ba soro, koda opo ara adugbo gan, beeni oko mi yoo si maa ki mi nilo wipe oun ko fe ri ajosepo kan laarin emi ati awon eniyan wonyi. Ni Akoko ti nkoi ti mo arakunrin yi daradara, ti mo ro wipe oro awada ni oro yi, emi a maa ba oko mi gbonu wipe, emi o le maa ba awon eniyan yondi lainidi o, sugbon nigba ti mo se akiesi wipe oko mi mu oro na ni okunkundun ni mo fi oro na to maami leti, maami si wa gba mi lamoran wipe ogbon ni n o da si oro na tori toko lase o, wipe ti oko mi ba ti soro nko gbudo maa gbo lenu, nse ni ki n daa lohun wipe mo ti gbo, ki n si mo bi n o ti maa fi ogbon ba awon ara ile mi lo ti ko fi ni da wahala si laarin emi ati oko mi.

Bayi ni mo bere sii daa bi ogbon, ti oko mi ba wa nitosi nse ni n o jina si awon eniyan wonyi koda oku Kiki kii pawa po. Ti oko mi ba si ti kuro nile, a o maa se ore ara wa, looto inu mi o dun si iru igbe aye yi, sugbon ki n maa ba da ile ara mi ru, mo nfi ogbon see.

Oro kan ni o wa sele ni ose keji seyin, arabinrin kan lara awon ayalegbe wa ni o ya kini ti a fi nlota lowo mi lati sure loo. Oko mi ko si nile ni akoko yi, ko pe si akoko yi ni oko mi wole, bi o ti wole de ounje ni o beere, beeni mo gbe ounje ka iwaju oko mi ti awa mejeeji si n jeun, bi a ti n jeun lowo, ni oko mi gbo ti enikan wa nidi ilekun, se oko mi ni o si sunmo enu ona? Beeni o si ilekun ti o si ba omo arabinrin ti o ya ohun elo ilota lowo mi, ti iyen si wipe mama oun ni ki oun muu fun momi.

Bayi ni oko mi bere sii wo omo yi, ti o si nwo emi na pelu tikategbin, ni mo nro ninu okan mi wipe, mo rogo loni, beeni mo sun mo omo yi ti mo si gba kini yi lowo re, ki oko mi to fo gbolohun kan, nko mo igba ti mo wipe “MI O YA WON O, MO GBAGBE RE SI ILE IDANO NI O” beeni oko mi tenu bo oro ti o si wipe:-

“Sebi mo kilo fun o, o fe gbo abi? Won ti so fun mi wipe alabodi ni e tele, o fe gba abodi fun mi abi? O fe pa mi ki o le jogun mi? Je ki nso fun o, ki o to pami wa jade kuro ninu ile mi, wooo mo njade lo bayi ki n to pada de, nko gbudo ba eyi ti o fuye ati eyi ti o wuwo ninu eru re ninu ile yi, bi bee ko, oku meji yoo ba Olorun nile”

Bi oko mi ti jade bayi ni mo pe egbon oko mi kan lori ago ti mo si kejo ro fun won, beeni awon pelu wipe bawo ni emi pelu yoo ti se bee niwon igba ti mo mo iru eniyan ti oko mi nse? Beeni egbon oko mi yi gbiyanju lati pee ki won baa soro sugbon o ti pa ero ibanisoro re. Bi oko mi ti pada de ti o ri mi bayi afi bi ekun ti o ri aja ni, ti ki baa se wipe mo sa jina loja ti a nperi yi ni Olorun nikan ni o mo ipo ti n o ba wa bayi, bayi ni oko mi bere sii ko ero mi sita ti kosi si enikan ti o lee daa lekun.

Bi ere bi awada bi mo ti dero ile wa ree o, bi mo ti pada de ile wa ni mo kejo ro fun maami, ti emi ati maami si bere si to ojule awon ebi oko mi kiri ki won le baa soro. Beeni won n pe oko mi lori ago loju wa sugbon nse ni o nso fun won wipe toba se lori oro mi ni, ki won ma yo oun lenu mo. Sugbon pelu gbogbo oro arakunrin yi maami ko sinmi bayi ni a gbera o di abule won lodo baba ti o bi oko mi gan, baba yi si wa je ki o ye wa wipe lati kekere ni iwa yi ti wa pelu arakunrin yi, sugbon tobe jube lo awon yoo baa soro, beeni won pe arakunrin yi ti won si baa soro, ti o si wa wipe oun ti gbo, mo le maa ko pada bo nile sugbon ota oun gbudo je ota mi ni, bi bee ko ajogbe po wa ko le rogbo.

Mo wa nda oro yi ro lati ano wipe iru igbe aye wo ni oluware yoo maa gbe bayi? Beeni maami pelu nfi ye mi wipe ohun ti oko mi ba ti fe ni mo gbudo baa fe, obe ti baale ile o kii je iyale ile kii se o, ko si si ile mosu nile wa o. Awon oro wonyi wa n je edun okan fun mi tori afi bi eni ngbe igbe aye inira ni oro na je, bawo ni n o se maa ba awon eniyan yondi lainidi? Gbogbo awon nkan wonyi ni mo nro, ati pada si ile arakunrin yi nse ni o dabi eni nlo si ogba ewon, iyen ni mo se ni ki nfi oro yi to eyin ojogbon leti, tori toba seese nko fe pada si odo ogbeni yi mo, beeni maami o je ngbadun, abi ki ni a o ti se eyi si? Iru ogbon wo gan ni a fi nba iru awon eniyan bayi gbe tori ko tie yemi mo bayi, e jowo e la mi loye o”

Hmmmmm oro ree o, eyin oloye eniyan, bawo ni a o ti se eyi si bayi? Eyin ojogbon eto Idile Alayo, se dandan ni wipe gbogbo eni ba je ota oko gbudo je ota aya re ni? Se gbogbo eniyan ti oko ba nbinu si ni iyawo re gbudo maa yan lodi ni? Sugbon looto iru ife wo ni ota eni le ni si omo eni? Hmmm eyin oloye eniyan e ba wa dasi o, se ki arabinrin yi tete tun ero ara re pa bayi ni abi ki o maa tele baba olofin yi???

`Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo