Home / Àṣà Oòduà / Gó́mìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá

Gó́mìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá

Aàrẹ Ọ̀nà Kakanfo, Ọ̀túnba Gàní Adams ti wọn ṣe ìwúyè fún ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, oṣù kini, ọjọ́ kẹtàlá ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún fi ẹ̀dùn ọkàn hàn nipa bi àṣà àti ìṣe Yoruba ti fẹ́ parẹ́.  Nigba ìwúyè, Ọ̀túnba Gàní Adams ṣe àlàyé pé́ ori ire ni wi pé kò si ogun ti ó nja ilẹ̀ Yoruba lọ́wọ́lọ́wọ́, ṣùgbọ́n òhun yio tẹra mọ́ṣẹ́ lati dáàbò àti bójútó àṣà àti ìṣe Yorùbá.

Ìpínlẹ̀ Èkó ti tún ta wọ́n yọ lẹ́ ẹ̀kan si.  Ni Ọjọ́bọ̀, oṣù keji ọjọ́ kẹjọ, ọdún Ẹgbàáléméjìdínlógún, Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin ti yio ṣe ìpamọ́ àti gbé èdè Yorùbá ga.

Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin – 

Gómìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé ju ọwọ́ lu òfin –

Akọ̀wé Yorùbá lóri ayélujára yin Gó́mìnà Akínwùnmí Àmbọ̀dé àti àwọn Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Èkó fún iṣẹ́ takuntakun ti wọ́n ṣe lati ṣe òfin fún ìpamọ́ àti ìgbéga èdè Yorùbá.

Continue after the page break for English version

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...