Home / Àṣà Oòduà / Idile Alayo ti Oni!

Idile Alayo ti Oni!

idele
Mo ki gbogbo wa ku isinmi opin ose mosi kiwa ku abo sori eto IDILE ALAYO ti oni. Gege bi ise wa atejise kan ti a ri gba ni a o ma ka siwa leti loni. E gbo bi o ti lo;-
“……..Mo ki Olootu eto Idile Alayo pupo wipe ogbon ati opolo ti e fi n dari eto yi ko ni daru lase Edumare! Mo si ki gbogbo awa Ololufe eto yi wipe bi a ti n fi imoran wa tun ebi elomiran se Eledua yoo tun ile ati ona enikookan wa se o AMIN. E jowo Olootu e foruko bomi lasiri, Odun ikefa re e ti mo ti wa nile oko, omo iketa si ni mo n to lowo bayi! Bi odun meta seyin ni a ko kuro ni ibi ti a ngbe tele nigba ti awon ijoba wipe ki won wo ile owun, odun ti a ko de ile tuntun ti a gba ni iya onile wa se alaisi, leyin bi osu mejo ti mama yi se alaisi ni omo mama yi kan ti o wa ni ile oko sa dede ko eru e pada si inu ile yi, ohun ti a si gbo ni wipe oko arabinrin yi ri i pelu okunrin miran ni o fi da eru e sita! Bi arabinrin yi se pada wa jogun ile iya e re e o ti o si wa di apase ile yi.

Ohun to tie wa ra emi ni temi re e o, ko ju osu mefa si meje ti arabinrin yi ko pade si ile yi ni mo n gbo iroyin wipe arabinrin yi pelu oko mi n ni nkan po, mo pe oko mi ni ikoko mo pe ni gbangba lati bi i leere oro yi sugbon oko mi ko jale, igba miran yoo da a si ibinu ni.

Hmmm se ti iro ba lo logun odun ojo kan soso ni otito yoo ba a, ni bi osu ikesan odun to koja ni mo n gbo ramirami wipe arabinrin na loyun fun oko mi, iro ni otito ni afi bi awon ebi oko mi se pe mi ni ojo kan ti won si parowa funmi wipe o ti sele wipe ki n gbiyanju lati mu mora ni o, hmmm leyin ti won pari oro won ni mo bi won leere wipe ibo wa ni arabinrin yi yoo ma gbe bayi sugbon nse ni olori ebi won dami loun wipe oro eyi ki i se oro oni wipe awon yoo sise lori yen laipe, sugbon si iyalenu mi n ko ri ise igbese kankan ti awon ebi wonyi gbe lori oro yi, ti mo si se akiesi wipe giragira arabinrin yi wa n po ninu ile paapa julo lori mi, ti o ba to akoko ti ile gbigba kan wa bayi ti a ko tete gba ile nse ni arabinrin yi yoo ma se epe lorisirisi wipe nigba ti iran won ko ko ile ri bawo ni won yoo se mo bi a ti n tun ti elomiran se!

Awon oro nla nla bayi ati omiran ni obinrin yi ma n so si emi ati awon omo mi, ni igba ti oro yi le koja aye mo pe oko mi mo si so fun un wipe ki o dakun bami wa ile miran tori ko le rorun funmi lati ma gbe ninu ile kanna pelu orogun mi to tun je iya onile wa sugbon nse ni oko mi yari kanle wipe oun o ni kobo ti oun yoo fi gba ile o, leyin igba ti n ko le fara da oro yi mo ni mo fi lo die ninu awon ore mi ti won si gbami lamoran wipe boya ki emi na gbiyanju lati wa owo ti n o fi gba ile, bi mo ti tepa mose re e o ti mo si fi oro na lo awon egbon mi ti awon na si fi owo die ran mi lowo sugbon ohun ti o wa je iyalenu mi ju ni wipe nigba ti mo so fun oko mi wipe mo ti ni owo die ti a le fi gba ile ni o daun wipe oun o ran mi nise o ati wipe oun o le fese kan ile owun, ti mo ba si gbiyanju e ki n mo wipe o ti tan laarin wa niyen, n o si gbudo ko awon omo toun lo, bi be ko gbogbo aye ni yoo bawa da si oro na.

Oro yi ba mi lokan je pupo mo si fi to awon ebi oko mi leti nse ni won wipe oro na ti koja agbara awon nitori oko mi ti bu olori ebi awon lori oro ile yi! Mo si fi oro na to awon obi mi leti sugbon nse ni won wipe toko lase o tori awon o gbadura ki n di ile mosu awon o si ni oko miran ti won yoo fun mi, iyen ni ironu se dori agba mi kodo, oro na wa toju sumi, koda nko ri orun sun lati ojo melo kan seyin nitori oro arabinrin yi toju sumi, awon omo mi si jemi logun pupo, n ko fe fi won sile fun iya je ati pelu nko fe ma ko kiri ile oko, iyen ni mo se to yin wa ki e lami loye o! Tori ko tie ye mi mo bayi!!
Hmmmm eyi tun ga o, abi e ri nkan afi ki Olorun ma saanu awa okunrin o…Eyin ojogbon o dowo yin oo

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*