Ilé Ẹjọ́ Gíga Orílẹ̀-Èdè Braṣil: Ẹ Dáàbò bo Ẹ̀sìn Ìbílẹ̀ Aláwọ̀ Dúdú
(Yoruba version by Akin Ogundiran)
Àbádòfin kan ti kalẹ̀ ní ìlú Rio Grande do Sul ní ilẹ̀ Braṣil tí yô ká àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ aláwọ̀dúdú lọ́wọ́kò láti máa pa ẹran rúbọ fún Òòṣà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ti fárígá pé àbádòfin yí kò tọ̀nà lábẹ́ òfin ilẹ̀ Brazil, èyí tó fún gbogbo ẹlẹ́sìn àti ẹlẹ́yàmẹ̀wà ní òmìnira láti jọ́sìn bí o bá ṣe wù wọ́n. Nítorí ìdí èyí, wọ́n ti gbé ilé aṣòfin ìlu Rio Grande do Sul lọ sí ilé ẹjọ́.
Ẹni tó gbé àbádòfin yí kalẹ̀, Regina Becker Fortunati, sọ wípé pípa ẹran rúbọ ń da àlááfíà ìlu láàmú, ó sì léwu fún ìlera ìlú. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ tákò ó wípé pípa ẹran rúbọ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí àwọn fi ńjọ́sìn, àti wípé ìlànà tí àwọn fi ńpa ẹran tọ̀nà ju bí àwọn alápatà ṣe ńpa ẹran fún ará ìlú jẹ. Wọ́n ṣe àfikún wípé ẹran tí àwọn fi ńbọ Òòṣà ni àwọn ńlò fún àsèjẹ, tí àwọn sì ńfi ìyókù bọ́ àwọn ará ìlú tí ebi ńpa. Nítorí ìdí èyí, ìdáábòbò fún àjẹyó àti ìlera ara ati ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni ẹran pípa fún ìjọ́sìn wà fún. Ilé ẹjọ́ gíga ti gbọ́ ẹjọ́ lọ́tǔn lósì. Ní ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹjọ ọdún yìí ni wọn yò ò dá ẹjọ́ yìí.
Ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yí ju ọ̀rọ̀ ẹran pípa lọ o. Láti nǹkan bi ọdún mélòó sẹ́yìn ni àwọn kán ti ńdojú ìjà kọ àwọn ọmọ ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ adúláwọ̀. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ni wọ́n ti lé kúrò ní ilé-ìwé, ilé ẹjọ́, àti àwùjọ gbogbo gbòò látàrí wípé wọ́n wọ àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ Òòṣà bí i ìlẹ̀kẹ̀. Àwọn onísùnmọ̀mín yìí ti yìnbọn lu àwọn olóòṣà, wọ́n ti lẹ ọ̀pọ̀ wọn lókúta; wọ́n sì tún ti dánásun ilé Òòṣà káàkiri, ká má tíì sọ ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ tí àwọn onísùnmọ̀mí yìí ńsọ káàkiri nípa ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀. Àbádòfin yìí jẹ́ ọ̀nà míràn tí àwọn olùkórìra wọ̀nyí ńgbà láti tẹ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ aláwọ̀ dúdú rì ní ilẹ̀ Braṣil.
Ó yẹ ká rán àwọn adájọ́ létí wípé òfin ilẹ̀ Brazil, pàápàá orí karùnún, fi ààyè gba gbogbo ẹ̀sìn, ó sì fún gbogbo ènìyàn ní ẹ̀tọ́ láti jọ́sìn ní ọ̀nà tó bá wù wọ́n. Nítorí ìdí èyí, a ńpè yín láti fọwọ́ sí ìwé àpilẹ̀kọ yìí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹnu wa yô kò láti sọ fún ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Brazil wípé ó ṣe pàtàkì láti dáábòbò ẹ̀sìn ìbílẹ̀ aláwọ̀dúdú. Ẹ̀sìn yí wà fún ọgbọ́n ìjìnlẹ̀, ìmọ̀, òye, àtúnbí, àti ìlera àwọn tó ńtẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Ọ̀kan nínú ògo ìlẹ aláwọ̀dúdú àti àwọn èèyàn rẹ̀ ni ẹ̀sìn yí jẹ́.
Igi gogoro má gùnún mi lójú, àtòkèrè lati wǒ. Ọ̀rọ̀ tó délẹ̀ yí kan ará ilé, ó kan ará oko. Ìkóríra àwọn aláwọ̀ dúdú àti àṣà wọn l’ó wà nídì àbádòfin yǐ. Ẹ jẹ́ ká kẹ́nu bò ó, kí àwọn adájọ́ lè mọ̀ wípé ó ṣe pàtàkì láti dáábòbò ẹ̀sìn, àṣà, àti ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní ilẹ̀ Brazil lápapọ̀.
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá wa tọwọ́ bọ ìwé yǐ ní orí ẹ̀rọ ayélujára:
Láti owó Akin Ogundiran.