Home / Àṣà Oòduà / “Ile ise MTN le kogba wole ti won ba sawon itanran tijoba pase re” – Minisita

“Ile ise MTN le kogba wole ti won ba sawon itanran tijoba pase re” – Minisita

Minisita tuntun fun eto ibanisoro, Ogbeni Bayo Shittu ti so wi pe ile ise MTN eka ti orileede Naijiria le kogba wo le ti won ba san owo itanran ti ajo ti n risi eto ibanisoro, Nigerian Communications Commission (NCC) ni kan san. Wahala sisan owo itanran yii lo ti n ja nile lati bi osu kan seyin saaju ki Ogbeni Shittu to gbase minisita.

Ajo NCC lo fesun kan ile ise MTN latari bi won se kunna lati gbegidina oju opo ila awon onibara bi milonu marun-un ti won ko foruko sile saaju gbedeke ojo ti won fun won lati se bee. Isele yii lo si sokunfa bi NCC se pase owo itanran to le ni bilionu marun-un owo dollar ile Amerika ni sisan.

Awon ile ise MTN ti n wa ona lati rawo ebe sijoba boya won le foju aanu wo oro to wa nile naa. Lose to koja loun, Igbakeji Aare ile Nigeria, Yemi Osinbajo joko pelu awon alase ile ise MTN ati ajo NCC lati se agbeyewo oro naa eleyii ti ko yori sibi to dun fun ile ise MTN. Ohun to tun sele leyin eyi ni bi oga yan-anyan ti ile ise MTN se kowe fipo sile nigba ti aibale okan wahala owo itanran naa ko je o le sun lale mo.

Ogbeni Shittu ni kii se idunnu awon ni kii ile ise MTN kogba wole. Iyoku si ku si ile ise naa lowo lori ona ti won fe gba lati ri oju rere ijoba.

“Gege bi minisita tuntun to sese gbase, awon ile ise MTN ko ti gbe oro naa wa siwaju mi. Monde, ojo Aje ti n bo yii si ni ijoba fun won di lati sanwo itanran naa”, Ogbeni Shittu fi kun alaye re.

Minisita lo seni laanu wi pe awon onibara ti MTN ko lati mu ila won kuro loju opo leyin ti won ko lati se akosile ila won lo je pupo awon eniyan ti won lo ila won fun ise ibi, eleyii ti awon Boko Haram naa wa ninu won.

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*