Home / Àṣà Oòduà / ILERA LORO: Bi a se le se itoju ehin enu wa

ILERA LORO: Bi a se le se itoju ehin enu wa

#Oniroyin
@OlayemiOniroyin

Aridaju iwadii ti fi ye wa wi pe osan orombo dara pupo ni mimu eleyii to n fun erigi ehin wa ni agbara.

Mimu osan orombo ran erigi lowo lati le mu ehin enu wa duro daada nipase orisii eroja vitamin C ti mbe ninu osan orombo.
Fifo ehin wa tun se pataki.

O kere tan, a gbodo maa fo ehin wa leemeji lojumo; nigba ta a ba fe sun lale ati igba ti a ba ji laaro putuputu.

Idi to fi se pataki lati maa fo ehin wa ka to sun lale ni wi pe, die lara awon ounje ti a je maa n ha si wa lehin.

Iru awon ounje bayii si maa n jera ki o to di ojo keji nigba to ba wa laarin ehin wa.

Awon ounje to ha si wa laaarin ehin yii si le se akoba fun ehin enu wa. Ko to di wi pe a bo si ori ibusun lale, e je ka fi ose ati igi ifohin fo enu wa nu daada.

Ti a ba n fo ehin wa pelu ose ifohin, agbodo maa ri daju wi pe a n fo ori ahon wa ati aja enu wa.

Awon idoti maa n le mo ori ahon wa eleyii to le fa ki enu wa maa run ti a ko ba fi igi ifohin gbo ori ahon naa daada.

Bakan naa ni oke enu ati isale ahon se pataki nigba ti a ba n fo enu nu, e je ka ri daju wi pe a n mu owo de gbogbo ibe pata.

Yato si wi pe a gbo ehin wa sotun ati sosi, a gbodo tun gbe igi ifohin wa si isale ehin nibi ti erigi pin si lati gbo ehin wa soke. Eleyii yoo fi anfaani sile fun awon idoti to ha si aarin meji ehin lati jade.

E ma gbagbe wi pe atinu atode ehin ni a o se eleyii fun ki gbogbo idoti naa le fo yo patapata.

Itoju enu wa se pataki, nitori ona kan pataki re e ti ounje n gba de inu ara wa. A si gbodo ri daju wi pe enu wa wa ni ipo to dara fun ilera wa.

Ojo mejo ni i ma tesiwaju nipa bi a se le se itoju ehin enu wa.

E ma gbagbe, Ilera loro.

@OlayemiOniroyin

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo