Home / Àṣà Oòduà / Ipade! Ipade! Ipade!

Ipade! Ipade! Ipade!

“Mo se ileri fun orisun mi
Ti I se ile yoruba,
Lati je omo yoruba atata nileloko,
Ati lati je omo oko,
Ti ki I f’owo osi
Juwe ile baba re,
Lati gbe ise, asa
Ati ede yoruba laruge,
Nibi gbogbo, ati kari aye,
Ki oluwa ki o ran mi lowo,
Lati mu ileri mi se. Amin”
A ki gbogbo wa ku ise oni, eledua yoo fere sise enikookan wa o. Ase.
A nfi akoko yi ran gbogbo ojulowo omo yoruba atata pata leti wipe, ojo abameta tii se ojo ikejilelogun osu ikewa ni ipade egbe omo yoruba atata ti osu ikewa yoo waye ni osu to nbo gege bi a ti ma n se losoosu, 22/10/2016.
Fun anfani awa ti a ngbo ikede yi fun igba akoko, egbe omo yoruba atata ti kuro ni egbe ori afefe lasan, nitori ete ati ero wa ni lati sa gbogbo ipa wa ni gbigbe ise, asa ati ede yoruba laruge ni orile ede yi ati kari aye. Kosi si bi a o ti se eyi lai ri ara wa soju, idi niyi ti a fi ma nko ara wa jo leekan laarin osu lati fijurinju, fikunlukun lati jo damoran lori bi egbe yi yoo ti di gbajugbaja kari aye.
Gbogbo omo kaaro ojiire ti o wa ni abala yi ti o si ni ife si gbigbe asa yoruba laruge ni o ni ore ofe lati kopa ninu ipade yi lai yo enikan sile.
Ojo ipade:- ojo ikejilelogun, osu ikewa odun yi (22/10/2016)
Ibi ipade:- ilu ikorodu, agbegbe igbogbo ipinle eko.
Akoko ipade:- ago mewa owuro
Olugbalejo:- isori “E”, tii se eka ikorodu
Ijuwe – ona:- lati ibikibi e wo oko “Motor” ti o losi ikorodu ki e bole ni ikorodu garage lati ikorodu garage ki e wo oko “Motor” ti o losi igbogbo ki e bole ni club 24. Ki e pe awon ero ibanisoro wonyi.
Fun alaye lekun rere ati ijuwe ona e pe balogun omo yoruba atata lori ero ibanisoro yi;- 08087002828
Tabi ki e pe arabinrin adeola a. Sambakiu lori ero ibanisoro yi:- 08185570848
Ki Eledua so gbogbo wa tayo ojo na, ohun buruku ti a ko ro ko ni ba ohun rere ti a nro je. A o ni rogun asurepe ki oja na to de, ni ojo na ati leyin ojo na lase edumare. Amin ase!

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo