Home / Àṣà Oòduà / Iriri awon omuti: Ore meji ku, iketa fara pa

Iriri awon omuti: Ore meji ku, iketa fara pa

Gege bi oro awon Yooba,”eni Sango ba toju re wole, eni naa ko ni ba won bu oba Koso laelae.” Okunrin kan to pe ara re ni Cde Zenzele Nkosi lori FACEBOOK lo salaye ijamba moto to sele si i nipa iwa oti mimu pelu oko wiwa. Okunrin naa se afihan foto oju-apa to gbe jade nibi isele naa eleyii to ti n jina. Bakan naa lo si n gba awon eniyan niyanju lati yago fun oti mimu pelu moto wiwa.

Ninu alaye Nkosi, okunrin naa salaye wi pe awon ore oun meji ti won wa pelu oun ninu oko naa lo ku, oun nikan ni ori koyo. Awon meji yoku ti padanu emi won danu latari wiwako-muti.

 

“Oko naa baje koja atunse, awon ore mi meji ti won wa ninu oko naa si ku loju-ese. Mo je oloriire lati wa laye. Too ba wako, ma muti; too ba muti, ma wako. Mimu oti wako je pakute iku ti n duro deni. Ti o ba fe wo oko ni akoko poposinsin odun taa wayii, ri daju wi pe direba re ko mu oti, o gbodo tun je eni ti ara re bale daada.  Gba mi gbo, ile aye yii ko too pon,” Nkosi fidi alaye re gunle bee.

 

Atejade Nkosi eleyii to se lojo keje osu kejila odun yii (7/12/15), ni nnka bi aago meta osan ku iseju mejila ni awon eniyan bi ogorun mefa (600) ti se atunpi atejade naa. Nigba ti awon eniyan bi ogofa (120) baa kedun labe iriwisi re titi di bi ago mokanla ojo Eti to koja yii ti OLAYEMI ONIROYIN se abewo si ikanni re lori ayelujara.

Die lara ikini ati ibanikedun ti awon eniyan se fun arakunrin naa ni yii:

M’lori Mlori Hardy: Cde…ki Oluwa fi orun ke awon to ti lo. Inu mi dun si bo se lo irora re lati fi se kilokilo ati ijigiri fun awon eniyan. Akoni loo se.

Sibiya Magoodies: Gbogbo ohun ti yoo sele seda laye lo ti wa ninu akosile Oosa Oke. Sugbon maa fi ope fun Oluwa wi pe o wa laaye lonii. Ki Oluwa bu tutu si okan awon eniyan ti won padanu awon eniyan won.

Orisun: Olayemioniroyin

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo