Home / Àṣà Oòduà / Iwosan ogbe inu

Iwosan ogbe inu

Awon nnkan won yii lo maa n se okunfa ogbe inu; ki eniyan maa fi ebi pa ara re nigba gbogbo, jije ounje gbigbona ati iyo pupo ninu ounje ati bee bee lo.

Bi a se maa se iwosan naa ni yii:

A ma wa ogede agbagba dudu ti ko ti pon meje (7). Leyin eyi, a ma bo epo ara re kuro. Ti a ba bo epo naa tan, la wa ma wa ge si wewe.

Awon ogede ti a ge si wewe la tun ma gun papo mo ara won. Leyin eyi la ma re sinu omi galoonu kan (4 liter).

O dindi ojo meta (3days) la maa fi re sinu omi naa. Leyin eyi la wa ma yo omi naa mu ni gbogbo igba.

Akiyesi pataki: Ti a ba ti bere si ni lo ogun yii, a gbodo dawo awon ounje to ba lagbara bi eba, fufu, iyan ati oti duro. Awon ounje to ba fuye bi iresi, tea, buredi ati opolopo miliki olope ni a gbodo maa je.

Gege bi mo se maa n so, Olayemi Oniroyin ko kose awo. Sultan akoroyin o kose isegun. Sugbo mo lagba nile, to ba ru mi loju mo lawon ojogbon ti won fun mi ni laakaye gidi.

Edumare nikan ni oluwosan to daju, oba oke yoo si fi alaafia to peye fun gbogbo wa. Ase

Ti e ba lo ogun yii to ba sise, e je ka mo. Ti e ba si mo ona mii, e so fun wa. Ire o!

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...