Home / Àṣà Oòduà / Iyawo olopaa gun oko re lobe pa niluu Akure: O ni ise esu ni

Iyawo olopaa gun oko re lobe pa niluu Akure: O ni ise esu ni

Okunrin olopaa kan ti eka ti Ipinle Ondo, Ogbeni Israel Omowa ni iyawo re, Arabirin Wumi Omowa ti gun lobe pa nibi gogongo orun oko re.

Ede aiyede kan lo waye laaarin toko-taya ti won gbe ni agbegbe Olu to wa laaarin masose Ilesa si Owo niluu Akure.

Titi di akoko ti iroyin yii fi n jade, enikeni ko ti le so pato ohun to waye laaarin won eleyii to mu iyawo re binu tan to si seku pa oko re laipe ojo.

“Iyawo olopaa ti le binu ju, gbogbo igba lo maa n kagidi bori bi faanu Taiwan. O ti to bi ojo meta kan ti a ti maa n gbo ariwo won laaaro-laaaro, enikeni ki i da si won mo nitori ko je tuntun. Sugbon eyi to sele yii jo wa loju, eleyii ti enikeni ko tile lero wi pe o le sele.” Obirin alamulegbe toko-taya yii, eni to ko lati daruko ara re lo so eleyii fun akoroyin Iwe Iroyin Owuro.

Alarinna ile ise olopaa ipinle Ondo, Ogbeni Femi Joseph ti jeri si isele naa.

Mista Femi so wi pe ile iwosan adani kan ti won gbe inpeto Israel Omowa lo naa lo pada dake si.

Okunrin to n sise alarinnna fun ile ise olopaa ipinle naa tun fi kun un wi pe iyawo olopaa naa ti wa ni gbaga awon olopaa bayii nibi ti ko ti ni alaye meji ti n se ju wi pe: “e saanu mi, ise esu ni.”

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo