Home / Àṣà Oòduà / Kayeefi: Adigunjale jabo lati oke aja banki sileele niluu Ilorin

Kayeefi: Adigunjale jabo lati oke aja banki sileele niluu Ilorin

Orisun
Okunrin afura si gege bi olosa kan lo jabo lati inu aja ile ifowopamo Guaranty Trust to wa niluu Ilorin lojo Eti to koja (09/10/15).

Kayeefi nla lo jo loju gbogbo awon eniyan to wa ninu banki ni akoko naa nigba ti maanu naa jabo po sile saarin banki bi ibepe to jabo lati ori igi.

Gege bi oro enu awon oluso banki naa, won ni o seese ko je wi pe lati oru ojo naa lo ti wa loke aja, eleyii ti enikeni ko si le so bo se de be.

Won ni o le je wi pe o n reti awon eniyan re to ku ti won jo fe ja banki naa lole sugbon ti ese re ye saaju akoko ti won da funra won.

Awon kositoma ti won nbe ninu banki naa ni won suru bo odaran afura si naa ko to di wi pe awon osise alaabo banki naa fi pamo de awon olopaa.

Alarinna ile ise olopaa ipinle Kwara, ASP Okasanmi Ajayi fidi isele naa mule wi pe otito ni.

O si salaye wi pe kete ti iroyin naa kan ile ise olopaa ni komisanna awon olopaa ipinle naa, Ogbeni Esosa Amadasun, ti yoju si banki naa.

Enikeni ko fara pa sugbon won ti gbe banki naa ti nigba ti awon iwadii abenu si n tesiwaju.

 

Orisun

About oodua

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Sanwo olu

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré

Ìpínlẹ̀ Eko ní ìfojúsùn ìpè pàjáwìrì ìsẹ́jú márùn-ún péré Yínká Àlàbí Ile-iṣẹ Aṣẹ ati Iṣakoso Pajawiri ti Ipinle Eko sọ pe awọn ti setan lati dahun si awọn ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko laarin isẹju marun-un pere.Olùdarí Àgbà fún ilé-iṣẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Femi Giwa, sọ èyí ní ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú awọn oniroyin ní ìlú Èkó.Giwa sọ pé àfojúsùn ilé-iṣẹ́ náà ni láti dín àkókò tó wà láàrín ìyè àti ikú kù nípa rírí dájú pé ìdáhùn náà wáyé láàrín ìṣẹ́jú ...