Home / Àṣà Oòduà / Kootu fi leta iku le Rev. King lowo

Kootu fi leta iku le Rev. King lowo

*Won ni ki won yegi fun un leyin to pa omo ijo re

Reverend King
Opin irin ajo ti de ba Rev. Chukwuemeka Ezeugo ti inagije re n je Reverend King nigba ti ile ejo to gaju yan-anyan, Supreme Court, tun fi onte lu u wi pe ki won lo yegi fun titi ti emi yoo fi jade lara re. Oludari ijo Christian Praying Assembly to kale siluu Eko ni ile ejo kotemilorun ti koko fi ontelu ejo ti ile ejo kootu ti da tele wi pe ki won yegi fun Rev King pelu bo se seku pa okan ninu awon omo ijo re, Ann Uzoh, ni ojo keji osu kejo odun 2006.

Oluso-agutan ti won pe ni Rev. King yii lo dana sun awon omo ijo re meje (7) kan latari wi pe o fi esun pansaga kan won. Ninu awon meje ti Rev King dana sun bi eran ileya ni Ann ti rekoja lo sorun aremabo.

Ejo ti won ti koko da lojo kerinla osu kinni odun 2007 wi pe, iku lere ese owo Rev. King. Sugbon maanu naa tun pejo kotemilorun lori ejo ti won da naa.

Nile ejo kotemilorun, ika eniyan kan ko ni lo lai jeya to to labe ofin ni adajo tun ko lorin seti Rev King.

Leyin eyi ni Rev. King tun fo fere lo si ile ejo Supreme to wa niluu Abuja boya Ifa won yoo fore yato si ejo ti won ti n da seyin.

Sugbon ibi pelebe naa ni abebe ti won so soke niluu Abuja tun fi n lele. Adajo ni ki won lo yegi fun un titi ti emi yoo fi jade lara Rev. Chukwuemeka Ezeugo ti gbogbo eniyan mo si Rev. King.

 

http://www.olayemioniroyin.com/2016/02/kootu-fi-leta-iku-le-rev-king-lowo.html

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*