Home / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Owonrin Tutu/ Oturupon

Odu Ifa Owonrin Tutu/ Oturupon

| |  | |
| |  | |
 |     |
| |   |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, eledumare yio gbo adura wa o yio si bawa tu ile aye to ti baje yi se o ase.
Odu ifa OWONRIN TUTU/OTURUPON lo gate laaro yi, ifa yi gba akapo ti odu ifa yi ba jade si niyanju wipe ki o se etutu daradara ki aye re baa le yi pada si rere, ifa ni aye inira ni akapo yi nje sugbon ti o ba rubo oro re yio pada dijo yio si dayo.
Ifa naa ki bayi wipe: Owonrin turupon turupon a difa fun Orunmila baba ntikole orun bo wa sikole isalaye, ile aye ko roju ona aye ko suhan won ni ki Orunmila karale ebo ni ki o se ki ile aye baa le tuba ki o baa le tuse, obi meji, eku, eja, igbin, ideregbe kan ati igba ewe ayajo Orunmila si kabomora o rubo won si se sise ifa fun, ko pe ko jina ile aye wa pada wa ndara ona aye si suhan baba wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe igbesi aye wa yio yi pada si daradara, gbogbo ona igbesi aye wa ti ko gun yio bere sini gun yio si toro, ako ni lo igbesi aye wa ninu inira o, eledumare yio bawa se itoju awon ibi to ti baje ninu igbesi aye wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? Hope it was graciously spent, I pray this morning that heavenly father will hear our prayers and replenish what had destroyed on the earth ase.
It is OWONRIN TUTU/OTURUPON corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice so that his/her life could be turn in a new leaves, ifa said the life of this person was so hard but it is only offering of sacrifice that will berate it.

 
Hear what the corpus said: Owonrin turupon turupon cast divined for Orunmila when he was coming from the heaven to the earth, when earth was tough and rough, he was advised to offer the sacrifice so that the earth may become sweet and suit, two kola nuts, mouse, fish, goat and ifa leaves, Orunmila complied, aftermath earth turned to good and everything was going on smoothly, Orunmila started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

 
My people, I pray this morning that our life shall turn in a new leaves, all the road of our life that are rough will becomes smooth, we shall never live in agony anymore, God will restructure the dilapidation of our life ase.

 

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

Òfún kò rẹ́tẹ̀ be yín

A kì í wípé kí ọmọ olówó kó má se yín gan-an gan-anBó bá ṣe yín gan-an gan-an a o ni fètè ìwọ̀fà boA dífá fún Ọ̀rúnmìlà wọ́n ní kí baba kó fi ẹbọ araa rẹ̀ sílẹ̀Wọ́n ní Ẹbọ ayé gbogbo ni kí baba o seỌ̀rúnmìlà ní kí ọmọ Osó kó mà kú oBaba ní k’ọ́mọ Àjẹ́ kó yèNítorí wípé ẹbọ ayé gbogbo ni mo nseIre oo