Home / Àṣà Oòduà / Ogbè Até

Ogbè Até

Owó òtún mi ni mo fi n gba ire
Adífáfún Sará Sará
N’ílé olódùmarè la gbé n báwon
Lóri orí eni òré òhun tìmùtìmù rere

Àtélewó mi òsì
Ni mo fi n gba ìfà
Adífáfún Sèbí Sèbí
N’ílé olódùmare ni a gbe n báwon
Ní orí ení òré òhun tìmùtìmù rere

P’ègbón P’àbúrò
kí ekún tó gbogbo ará ilé sun
Òhun náà n re’lé olódùmarè
Ebo ni won ní kó se

Ewí fún sará sará
Kóya tárá è se
Ewí fún sèbí sèbí
Kóya tún ìbí è se
Ìkà n be ni bodè
Tí n r’ojó.

About Awo

x

Check Also

Egbé agbá bóòlú fún orílè èdè Nìjíríà àti ti Cameroon: Ìghàló gégé bíi òdómokùnrin tí ó gbégbá orókè nínú eré bóòlù náà.

Egbé agbá bóòlú fún orílè èdè Nìjíríà àti ti Cameroon: Ìghàló gégé bíi òdómokùnrin tí ó gbégbá orókè nínú eré bóòlù náà. Omo egbé agbá bóòlù fún orílè èdè Nìjíríà tí na àwon omo egbé agbá bóòlú Cameroon ní méta sí Méjì, (3-2), ní gbàgede pápá ti Alexandria láti le wo ìpele kèta sí ife. Jude Odion Ighalo ló gbá méjì wo ilé àwon alátakò won, tí Alex Iwobi sì gbá ìkan tí ó kùn wolé. Nse ni ó dàbí ...