Ara opo awon omo Naijiria tun ya gaga si orile ede won lojo Alamisi to koja, nigba ti a se ayeye ominira odun karunlelaadota.
Kaakiri awon ipinle, opo eniyan lo ki akegbe won ku oriire, ti won si n soro lori ireti pe nnkan yoo pada bo sipo fun Naija.
Awon onmoran woye pe igbagbo ninu ijoba Aare Muhammadu Buhari lo fa eyi, tori awon eniyan gba pe o fe fi otito inu tun ilu to.
Idi niyii ti ko fi yani lenu pe opo eniyan lo ra asia Naijiria, ti won si ta a si ara moto won.
Lori ero alatagba intaneeti naa, awon enyan n kira won, ti won si n ka aseyori Buhari.
Odun 2015 yii ko ni igba akoko ti orileede Naijeria yoo maa yo ayo ominira. Odun eyi to wole lo je odun marundinlogota (55) ti ilu awon eniyan dudu to poju lo lagbaaye yoo maa yo ayo bibo lowo awon oyinbo amunisin.
Bi o tile je wi pe teru-tomo pata ni won fo fayo lojo kinni osu kewaa odun 1960 latari akikanju, ifomoniyanse ati ilakaka awon akoni igbaani bi Nnadi Azikiwe, Obafemi Awolowo ati Ahamadu Bello; sugbon nigba to ya, irewesi n de ba awon omo Naijiria nipa yiyo ayo odun ominira eleyii ti opolopo gba gege bi omi inira.
Eleyii ko sadeede waye, jegudujera, riba gbigba, ojelu, aisododo, ainife ara ilu to gbile laaarin awon alase ati olori ile yii lo bu omi tutu si okan awon eniyan.
Aimoye ibeere ni awon eniyan n beere lati ojo pipe eleyii ti enikeni ko ri idahun si. Kilode ti Naijeria to kun fun wara ati oyin n sun lebi? Kilode ti omo eleran n jeegun? Kilode ti omo alaso alaari wo akisa kiri igboro?
Leyin eto idibo aare to waye lojo kejidinlogbon osu keta odun ta a wa yii, igbagbo awon eniyan ko ja wale eleyii to fun ireti awon ara ilu lagbara ninu isejoba Aare Muhammed Buhari.
Bi o tile je wi pe o pe ki Buhari to yan awon minisita ti won yoo jo maa sise gege bi igbimo, sibesibe iyipada to loorin ko sai foju han nipa ina monamona, igbogun ti iwa jegudujera, ifese mule eto abo ati igbenusoke eto oro aje bi baalu to setan ti o fo soju orun.
O ku ojo bi meloo kan ti ayajo ominiran odun yii yoo wole, bee ni atejade kan bere si ni fo kiri ori ero ayelujara eleyii to n se afihan iye owo ti ijoba to kuro loye, Ijoba Goodluck Jonathan, ti i na lori ayeye ayajo ominira ati eleyii ti aare tuntun to wa lode yii setan lati naa fun ayeye kan naa.
Atejade naa ni yii:
Ijoba Jonathan 2011:
Bilionu metala (13b)
Ijoba Jonathan 2012:
Bilionu meedogun (15b)
Ijoba Jonathan 2013:
Bilionu merinla (14b)
Ijoba Jonathan 2014:
Bilionu mejilelogun (22b)
Ijoba Buhari: 2015:
Aadorin Milionu (70m)
Awon iroyin to jade yii tun bo mu inu opolopo dun eleyii mu won jigiri si ajoyo ayajo ominira odun yii ju ti ateyin wa lo.
Sugbon sa, ajoyo ayajo odun ominiran ko fi bee rinle ni awon ipinle bi Osun ati ipinle Oyo.
Sebi awon Yoruba bo, won ni aja ti o yo kii ba eyi ti ko yo sere. Bi ijoba awon ipinle naa se je awon osise lowo ko je ki inu awon eniyan dun debi wi pe ara won yoo ya gaga.
Sebi bi oode ko dun, bi igbe niluu ri.
Orisun: Olayemioniroyin.com
One comment
Pingback: ccn2785xdnwdc5bwedsj4wsndb