Home / Àṣà Oòduà / Òṣìṣẹ́ mẹ́rin bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ọ̀gá wọn tó rì sómi

Òṣìṣẹ́ mẹ́rin bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ọ̀gá wọn tó rì sómi

Ìgbákejì Ọ̀gá Àgbà iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó orí, Price Water Coopers , PwC Nigeria , Tola Ogundipẹ ti jáde láyé.

Ọjọ́ Sátidé ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá arákùnrin náà lẹ́yìn tó wọ ọkọ̀ ojú omi ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Ọjọ́ Àìkú ni wọ́n rí ọkọ̀ ojú omi náà, àmọ́ tí àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ lórí omi sì rí òkú rẹ̀ ní Ọjọ́ Ajé.

Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Muyiwa Adejọbi sọ wí pé, lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, àwọn òṣìṣẹ́ olóògbé mẹ́rin ni àwọn ti fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò.
Ó sàlàyé wí pé, Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu ti pàṣẹ ìwádìí ìdákọ́ńkọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

” A ti gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwà ọ̀daràn ní Yaba, nípìńlẹ̀ Èkó láti ṣe ìwádìí náà ní kíkún.”

”Tí ìwádìí bá parí, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóó fi àbájáde hàn sí gbangba.”

Nínú ọ̀rọ̀ tí iléeṣẹ́ Price Waterhouse Coopers fi léde, Ọ̀gá àgbà pátápáta ní Nàìjíríà, Uyi Akpata sàpèjúwe Ogundipẹ tó d’olóògbé náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dójú àmì.

Kó tó di olóògbé, Tola Ogundipe ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí ẹ̀ka “PwC Africa Tax , Assurance Leader for PwC Africa” àti àwọn ipò míràn tó dìmú nínú iléeṣẹ́ PwC.

Iléeṣẹ́’ Price Waterhouse Coopers” ní àwọn yóó fi ọjọ́ ìsìnkú rẹ̀ léde lẹ́yìn ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ará olóògbé náà.

Fẹ́mi Akínṣọlá

About ayangalu

x

Check Also

tirela

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa

Tírélà jábọ́ láti orí afárá l’Eko, rún Korope méji pa Fẹ́mi Akínṣọlá Aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ló ń lọ lu lọjọ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kerin 2025, tírélà kan fi jábọ́ láti orí afárá Pen Cinema, Agege, l’Ekoo, tó sì run ọkọ̀ Kórópe méjì tó jábọ́ lé lórí pa. Ajọ Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Atẹjade kan ti Adari iṣẹlẹ bi eyi ati ilaniloye ni LASTMA, Adebayo Taofiq, fi ...