Ní òwúró ojó àíkú tí se èní,ojó kokàndínlógbòn osù keje odún 2018 ni òjò yí bèrè tí ó sì kò tí kò dáké di bíi agogo márùn-ún ìròlé.
Èyí fa kí àgbàrá ya wo ilé tí ó pò ní òpópónà Ede sí ifè, àti ònà tí a mò sí road 7, àti àwon ònà míràn, Ó tilè ti férè gba ilé míràn lówó onílé.
Tí ó bá je wípé ó ńkó wólo ni Ó sì dára, sùgbón kò wó lo bíkòse wípé ó dúró sí ojú kan tí kò sì lo, báwo ni àwon tí ó wà nínú ilé se ma jáde àti wípé báwo ni àwon tí ó wà ní ìta se ma w’olé?
Ìsèlè yí, nínú ìwádìí a gbó wípé èyí kó ni àkókò tí omi ma w’olé tí àgbàrá sì ma wo sóòbù ní ilé ifè ìlú tí ó wà ní ìpínlè Òsun ní orílè èdè Nìjíríà.
Kí ni ó le fa èyí? Sé ònà tí kò dára ni àbí àílè se ònà tí ó ye kí àgbàrá ma gba, èyí mà le poo, ní ìlú tí mùndùnmúdùn gbé ń sàn fún wàrà àti oyin, “èbè ni a be àwon ìjoba wa kí won bá wa mójú tó àwon ònà yí nítorí olórun” báyìí ni àwon ará ìlú ńké.
Ko tiri, me man koru ye n’fe