Home / Àṣà Oòduà / Omo ìbàdàn

Omo ìbàdàn

Omo ìbàdàn

Ìbàdàn mèsi ògò, n’ílé olúyòlé.
Ìlú ògúnmólá, olódò kèri l’ójú ogun.
Ìlú ìbíkúnlé alágbàlá jáyà-jáyà.
Ìlú Àjàyí , ò gbórí Efòn se fílafìla.
Ìlú Látóòsà, Ààre-ònà kakanfò.
Ìbàdàn Omo ajòro sùn.
Omo a je ìgbín yó, fi ìkarahun fó ri mu. ìbàdàn májàmájà bíi tojó kín-ín-ni,
èyí tó ja aládùúgbò gbogbo ológun
Ìbàdàn kìí bá ni s’òré àì mú ni lo s’ógun.
Ìbàdàn Kure!
Ìbàdàn bèèrè kí o tó wò ó, Nibi Olè gbé n jàre Olóhun.
B’íbàdàn tí ń gbonįlé béè ló n gbe Àjòjì.
Eléyelé l’omi tí t’erú-t’omo ‘Láyípo ń mu. Àsejíre l’omi abùmu-bùwè n’ílè ìbàdàn.

About Awo

One comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

*

x

Check Also

Aáyẹ tí ó de bá àṣà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àṣà máa ń yí padà nípa aṣo wíwọ̀, ìgbéyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lóde-òní, ètò ẹ̀kọ́ àti ìwà ọ̀làjú tó gbòde kan ti ṣe àkóbá fún àṣà ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí: (a) Ìwọsọ wa kò bójú mu mọ́. (b) Àṣà ìkíni wa kò ní ọ̀wọ̀ nínú mọ́. (d) Kí’yàwó ilé má mọ oúnjẹ ìbílẹ̀ ṣè mọ́. (e) A kò mọ ìtumọ̀ àrokò tí a ń kọ́ àwọn ọmọ wa mọ́. (ẹ) A kò fi èdè ...